Amina dana sun ile ọkọ rẹ, o ni ko fẹẹ kọ oun silẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 15, 2023

Amina dana sun ile ọkọ rẹ, o ni ko fẹẹ kọ oun silẹ


Iyaale ile, ẹni ogun ọdun kan, Amina Hassan ti ṣalaye pe bi ọkọ oun ṣe kọ lati kọ oun silẹ lẹyin adehun ti wọn jọ ṣe lo jẹ koun binu dana sun ile rẹ.
 
Amina, nigba to n sọrọ ṣalaye pe adehun to wa laarin ohun ati ọkọ oun, Muhammed Auwal ni pe awọn yoo kọ ara wọn silẹ lẹyin ti wọn ba ṣe igbeyawo.

O ni ọsẹ marun-un sẹyin ni awọn ṣe igbeyawo, toun si n reti wi pe ko kọ oun silẹ, gẹgẹ bi adehun ṣugbọn to sọ pe ko le ṣee ṣe.

Amina, ọmọ bibi agbegbe Shuware nijọba ibilẹ Mubi North ni wọn sọ pe ko tii ṣetan lati ṣe igbeyawo pẹlu ọkọ rẹ, ṣugbọn lati fi tan awọn obi rẹ lo jẹ ko gba.
 
O ni kaka ki ọkọ oun tẹle adehun wọn lati kọ oun silẹ, niṣe lo tun bẹrẹ sii lu oun, idi ree to loun fi binu s'odi, toun si lọ dana sun ile ọhun.

Suleiman Nguroje nigba to n sọrọ sọ pe Amina ti wa lahamọ awọn, o si ti n sọ ohun to tun le fi ran wọn lọwọ, ko to di pe o foju ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI