Oni tii ṣe ogunjọ, osu kọkanla, ọdun 2023 lo gbe ogunjọ ti gbajugbaja sọrọsọrọ nipinlẹ Ogun, Jẹleel Angel Ajayi bẹrẹ kika iroyin fun ọgbọn ọjọ lai sinmi, eyi ti ko tii ṣẹlẹ ri kaakiri agbaye.
Aago mẹfa owurọ, ọjọ kinni, oṣu kọkanla ti a wa yii ni ọmọ bibi ilu Imaṣayi nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ipinlẹ Ogun to n ṣeto nileeṣẹ redio mọlẹbi, Family 88.5FM bẹrẹ kika iroyin lede abinibi, iyẹn Yoruba fun ọgbọn ọjọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, kika iroyin lede abinibi ni ileeṣẹ redio fun ọgbọn ọjọ kii ṣe ohun to ṣẹlẹ ri lagbaye.
Gbogbo awọn iroyin Yoruba ti wọn n ka nileeṣẹ redio mọlẹbi lati ọjọ kinni, oṣu kọkanla, ọdun 2023 lo jẹ pe ọmọkunrin kan ni yoo ka a fun ọgbọn ọjọ.
Bi wọn ba n darukọ awọn sọrọsọrọ ori redio ti ede Yoruba dantọ lẹnu wọn, paapaa nipinlẹ Ogun, ọkan pataki ni Angel Ajayi jẹ, kii ṣaimọ foloko.
Angel si fẹran lati maa ṣe ohun ti ẹnikan ko ṣe ri, paapaa nidi iṣẹ to yan laayo.
Ẹwa ede, aṣayan ọrọ, owe ati oniruuru ohun to n mu ki iṣẹ igbohunsafẹfẹ dun mọ araalu ni ẹbun ti Ọlọrun fi jinki Ajayi, idi ree ti awọn eeyan fi n gba tiẹ.
Agogo mẹfa owuro si agogo mẹwaa aṣalẹ ni Angel fi n ka iroyin lojoojumọ, bayii si ni yoo ṣe fun igba ti ọjọ naa yoo fi pe.
Nigba toun funra rẹ n sọrọ, o ni kii ṣe pe oun fẹẹ ka iroyin ti ẹnikẹni ko ka ri naa lati fi gba ami ẹyẹ agbaye ti a mọ si Guiness World Records, ṣugbọn lati jẹ ki awọn ololufẹ oun mọ pe ko si nnkan toun ko le ṣe.
O ni kii ṣe ohun to rọrun lati ṣe, nitori pe oun kii fi bẹẹ ri aye lati sun, bẹẹ si lo jẹ pe ojukan loun yoo wa nibi toun ti n palẹmọ fun iroyin tuntun, fun igbadun araalu.
Pupọ awọn ilu mọn-ọn-ka ati gbajumọ lawujọ ni wọn ti yọju si Angel lati lu lọgọ ẹnu, ti wọn si n gbe oṣuba kare fun un lori igbesẹ to gbe yii.
No comments:
Post a Comment