Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kootu daṣẹ silẹ l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 22, 2023

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kootu daṣẹ silẹ l'Ọṣun


Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile-ẹjọ labẹ aburada Judiciary Staff Union of Nigeria, JUSUN, nipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iyanṣẹlodi.
 
Oni, ỌJọru, Wẹside ni alaga ẹgbẹ naa, Oluwagbenga Ọlakunle Eludire kede iyanṣẹlodi naa.
 
Iyanṣẹlodi yii lo bẹrẹ latari iwọde ifẹhonuhan ti wọn ṣe lọjọ Aje, Mọnde ati Tuside, ọsẹ yii lori ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan adajọ agba ipinlẹ naa, Onidajọ Oyebọla Adepele Ojo.
 
Lara awọn ẹsun ti wọn tun fi kan adajọ agba naa ni bo ṣe n ṣe awọn oṣiṣẹ lọna aitọ bii aisan owo idanilẹkọọ, owo ajẹmọnu ati owo aṣọ laarin ọdun 2021 ati 2023.
 
Bakan naa ni wọn lo tun kọ lati da awọn to da duro pada sẹnu iṣẹ wọn.
 
Wọn wa lawọn fẹ ki eto igbega laarin awọn oṣiṣẹ ile-ẹjọ bẹrẹ, ki wọn si san gbogbo ẹtọ ti wọn ti jẹ wọn loju ẹsẹ.
 
Eludire ti wa paṣẹ pe ki gbogbo oṣiṣẹ ile-ẹjọ jokoo sile titi digba ti ijọba yoo fi gbọ ẹbẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI