Ọwọ tẹ baba agbalagba to fipa ba alaabọ ara laṣepọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 23, 2023

Ọwọ tẹ baba agbalagba to fipa ba alaabọ ara laṣepọ


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa ti rọwọ to baba agbalagba, ẹni ọdun mẹtalelaadọta kan, Usman Ahmadu lori ẹsun wi pe o ba ọmọdebinrin alaabọ ara kan laṣepọ.
 
Baba naa, ọmọ bibi ilu Maiduguri nipinlẹ Borno to n gbe lagbegbe awọn ti ogun le kuro niluu, iyẹn IDP to wa ni Saminaka lẹyin odi ilu Yola, Ariwa Yola lo ti bẹrẹ sii ka boroboro.
 
Wọn ni ọmọdebinrin naa ni aisan ọpọlọ, eyi to jẹ ki Usman ri anfaani lati ba a laṣepọ.

Ẹẹmẹrin ọtọọtọni wọn sọ pe Usman ti ba ọmọ naa laṣepọ lati ọdun 2021 si ọdun 2023

Nigba to n sọrọ ninu atẹjade ti Suleiman Ngoroje to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa fi sita, kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Afọlabi Babatọla sọ pe Usman ti wa nibi to ti n ka boroboro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI