Adron Homes gbe New York wọ ilu Keffi, pẹlu ọpọlọpọ anfaani fun ayẹyẹ ọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 15, 2023

Adron Homes gbe New York wọ ilu Keffi, pẹlu ọpọlọpọ anfaani fun ayẹyẹ ọdun


Ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited to n ta ilẹ, ile ati dukia kaakiri agbaye tun ti gbọna ara ọtun yọ niluu Keffi, ipinlẹ Nasarawa pẹlu bi wọn ṣe gbe New York wọ ilẹ naa.

Ọpọlọpọ anfaani ni wọn mu wọ inu ọgba ilẹ wọn ti wọn pe ni New York Park and Gardens fun anfaani araalu lati di onile lori lasiko ayẹyẹ ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun to n bọ lọna.

Gẹgẹ bi a ṣe mọ, ilẹ Amerika ni ilu ti wọn n pe ni New York wa, nibi ti awọn eeyan kaakiri agbaye maa n rin irin ajo afẹ lọ.

Bi wọn ba si n darukọ awọn ilu ti wọn rẹwa julọ lagbaye pẹlu eto ọrọ aje to munadoko, ọkan pataki ni New York jẹ.

Idi ree ti ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited ṣe wo o pe ki awọn mu lara awọn anfaani ti awọn eeyan n jẹ nibẹ wa Naijiria fun irọrun araalu.

Ko fẹẹ si ohun to wa niluu New York lorileede Amẹrika ti ẹ ko ni ba ni New York Park and Gardens ti Adron Homes gbe kalẹ niluu Keffi.

Eto aabo to pe ye, ayika to jọju, awọn ohun iṣere ati igbafẹ igbalode, ina mọnamọna ti kii ṣẹju lọsan ati lalẹ, awọn aramanda aworan ati bẹẹbẹẹ lọ.

Yatọ si awọn nnkan wọnyi, awọn ile awosifila igbalode ko gbẹyin ni New York Park and Gardens yii.

Ileeṣẹ Adron Homes ti wa ṣagbekalẹ ọna irọrun fun awọn onibara lati san ilẹ nibẹ lai laagun rara fun oṣu mejila tabi oṣu mẹrinlelogun.

Anfaani naa lo tun papọ mọ Lemon Friday to n lọ lọwọ bii ida ogoji (40%) ti awọn onibara yoo san fun oṣu mejila, ti yoo si tun gba baagi irẹsi, adiẹ to lọ nibamu pẹlu sisan ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira fun igba akọkọ 

Lata awọn ibi anfaani yii tun ti n lọ ni; Ibeju-Lekki, Epe, Badagry, Ede Osun, Ado Ekiti, Shimawa, Atan-Ota, Ikorodu, Shagamu, Papalanto, Ijebu Ode, Abeokuta, Ibadan, Abuja ati Nasarawa, Niger.

Fun alaye lẹkunrẹrẹ, ẹ kan si awọn alakoso yala lori ikanni ayelujara wọn ni tabi awọn ẹrọ ibanisọrọ wọnyi.

Facebook Adronhomesofficial, Twitter @adronhomes and Instagram @adronhomesofficial or visit our website at www.adronhomesproperties.com to read more. Or simply call: 07032290311, 08022122490, or 08033588328.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI