Bi Yoruba ba ṣe ara wọn ni oṣuṣu-ọwọ, itẹsiwaju yoo wa - Ọtunba Ọdunowo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 5, 2023

Bi Yoruba ba ṣe ara wọn ni oṣuṣu-ọwọ, itẹsiwaju yoo wa - Ọtunba Ọdunowo


Ọkan lara awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ Ogun, Ọtunba Adebayọ Ọdunowo ti rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ Yoruba patapata lati ṣe ara wọn ni oṣuṣu-ọwọ fun itẹsiwaju.

Gbajugbaja oloṣelu naa lo sọrọ yii niluu Omu-Ijẹbu, ijọba ibilẹ Odogbolu n'ipinlẹ Ogun, lasiko ti ikọ ẹgbẹ Afẹnifẹre ti ẹkun Ikẹnnẹ ati Odogbolu ṣe abẹwo sii.

Nibẹ lo ti sọ pe ki awọn to n ṣakoso ẹgbẹ Afẹnifẹre lasiko yii fi aaye gba awọn ọmọ Yoruba tuntun lati darapọ mọ wọn, fun idagbasoke ati ilọsiwaju.

Ọtunba Ọdunowo ni ẹgbẹ Afẹnifẹre jẹ ẹgbẹ kan to gbajumọ julọ ninu awọn ẹgbẹ to n ṣe igbelarugẹ fun ẹya lorileede Naijiria ko to di pe awọn oyinbo alawọ funfun de.

O ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ naa pada si bi awọn to da ẹgbẹ Afẹnifẹre silẹ ṣe bẹrẹ, lati le ṣe aṣeyọri rere lori afojusun ti wọn fi da a silẹ.

Bakan naa lọ rọ awọn ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre lati ṣiṣẹ takuntakun lori bi ede Yoruba yoo ṣe pada bọ sipo, ko ma baa dimẹri, ati pe ki awọn eeyan dẹkun lati maa pe ede Yoruba ni ede ti ko dara lati sọ.

O ni boun ṣe ti rin irin ajo kaakiri agbaye ti jẹ koun mọ pe awọn ilu toun lọ ko fi ede wọn ṣere, ati pe bi awọn ọmọ Naijiria ba lọ si awọn orileede miran, wọn ni lati kọ ede wọn nibẹ fun bi oṣu mẹfa ko to di pe wọn bẹrẹ sii lọ sile-ẹkọ.

Bẹẹ lo dupẹ lọwọ awọn aṣaaju Afẹnifẹre ọhun lori abẹwo ti wọn ṣe sii, to si loun mọ riri wọn daadaa.

Lara awọn to wa nibẹ ni Oloye Ebenezer Ogunlana; Arabinrin Funmilayọ Ṣoyewo; Ọmọọba F. Adesanya; Ọmọọbabinrin Olubunmi Olujọbi; Arabinrin Ọmọwunmi Ọlawale; Arabinrin Ajani Ọlabisi; Ọgbẹni Adeleke Ṣosan; Arabinrin Ọladipupọ Ọlayẹmi; Ọgbẹni Adeṣina Francis Ṣofuyẹ; Ọgbẹni Adedoyin Ọrẹlaja ati Ọgbẹni Oluwọle Adelọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI