Owo ipolongo idibo 2023 ti wọn ko jẹ lẹgbẹ oṣelu PDP di wahala ni Kwara, ni olori awọn ọdọ ba loun ko ṣe ẹgbẹ mọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 12, 2023

Owo ipolongo idibo 2023 ti wọn ko jẹ lẹgbẹ oṣelu PDP di wahala ni Kwara, ni olori awọn ọdọ ba loun ko ṣe ẹgbẹ mọ


Olori awọn ọdọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Kwara, Ọmọọba Haliru Dantosho Mahmud ti kọwe fipo silẹ, to si loun ko ṣe ẹgbẹ naa mọ.

Ninu lẹta ti Ọmọọba Mahmud fi ranṣẹ si alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọọdu Kaiama kinni lọjọ kọkanla, oṣu kejila, ọdun 2023, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti tun ṣalaye pe awọn kan n fi iku wa oun kaakiri.

Mahmud to tun jẹ Dan Iyan tiluu Kaiama sọ pe lara idi pataki toun fi kọwe f'ẹgbẹ silẹ ni bi aṣiwaju ẹgbẹ n'ipinlẹ naa, Oloye Bukọla Saraki ṣe kọ lati ṣe akọsilẹ bi wọn ṣe na owo ipolongo eto idibo ọdun 2023.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe bi Saraki to jẹ olori ile igbimọ aṣofin Naijiria tẹlẹ ba tẹsiwaju lati maa ṣakoso ẹgbẹ bo ṣe n ṣe e, ẹgbẹ PDP ko tun le rọwọ mu ninu eto idibo to ba waye ni Kwara.

Lẹta ọhun ree


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI