Ijọba Kwara tun pin apo agbado ẹgbẹrun lọna ogun fun araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 12, 2023

Ijọba Kwara tun pin apo agbado ẹgbẹrun lọna ogun fun araalu


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti paṣẹ pe ki wọn pin apo agbado ẹgbẹrun lọna ogun fun gbogbo araalu, to jẹ lara eto iranwọ ti ijọba apapọ ṣagbekalẹ rẹ.

Idaji iye owo ti wọn n ta apo agbado ti ko din ni aadọta kilogiramu (50kg) ni ijọba fẹẹ gbe awọn agbado yii silẹ fun araalu, fun igbelarugẹ iṣẹ agbẹ ati ọgbin.

Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni awọn igbimọ to n ri sọrọ pinpin awọn agbado yii pin fawọn araalu.

Ẹgbẹrun marundinlọgbọn baagi ni wọn pin ni ipele akọkọ loṣu diẹ sẹyin.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni apo agbado kan to ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn (₦26,000) naira lọja, ṣugbọn ti araalu yoo san ẹgbẹrun mẹwaa naira pere lati mu idẹrun ba wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI