Ile ẹjọ Kabusa Grade I to wa niluu Abuja ti paṣẹ pe ki Chris Okoye, ẹni ọdun mẹrinlelogoji lọ gbatẹgun diẹ lọgba ẹwọn lori ẹsun wi pe o lu baba lanlọọdu ẹ.
Onidajọ Malam Abubakar Sadiq lo gbe aṣẹ naa kalẹ lonii, ọjọ Ẹti, Fraide, lẹyin to gbọ ẹbẹ Chris.
Okoye to n gbe lojule keji akọkọ Nigeria Avenue Villa Nova, Apo ni wọn fi ẹsun ija, idunkooko, dida apa si eeyan lara ati awọn ẹsun miran kan.
Bo tilẹ jẹ pe o bẹbẹ wi pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, sibẹ, Onidajọ naa sọ pe ko ṣi lọ gbatẹgun diẹ lọgba ẹwọn titi digba ti igbẹjọ yoo tun waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kinni, ọdun ti a wa yii.
Agbefọba to fẹsun kan Chris, O.S. Osho ti kọkọ sọ fun ile-ẹjọ wi pe baba onile naa, Ọgbẹni Ochengele Isaac lo lọ fi to awọn ọlọpaa Apo leti lọjọ kẹta, oṣu kinni, ọdun 2024 wi pe Chris lu oun lalubami.
Ọshọ ni baba naa ṣalaye pe Chris ati awọn ọmọ rẹ meji pẹlu ẹnikan to n jẹ Gideon toun ti na papa bora ni wọn jọ dawọ bo lanlọọdu, ti wọn si lu.
Agbefọba naa fi kun ọrọ rẹ pe awọn ọmọ meji naa tun ti na papa bora pẹlu.
No comments:
Post a Comment