Ijọba Ọṣun rọ ọba mẹta l'oye lẹẹkan ṣoṣo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 20, 2024

Ijọba Ọṣun rọ ọba mẹta l'oye lẹẹkan ṣoṣo


Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ohun ko nii yi ohun pada lori irọloye awọn meji ti wọn gbọna eru j'ọba.

Agbẹnusọ ogomina,Ọlawale Rasheed lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to gbe sita lọjọ Ẹti, Fraide, ọsẹ yii niluu Oṣogbo.

Laipẹ yii ni ijọba Ọṣun gbe atẹjade sita wi pe ohun ti wọgile iyansipo Aree tiluu Iree ati Ọwa tiluu Igbajo, pẹlu bo ṣe ni ọna ti wọn gba yan wọn ni awuruju ninu.
 
Bakan naa ni ijọba tun sọ pe ipo ki ipo Akirun tiluu Ikirun, ti Ọba Ọlalekan Akadiri ti ṣofo bayii, titi digba ti idajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun yoo fi waye.
 
Rasheed, lo sọ eyi di mimọ lori awọn ayederu iroyin to n lọ kaakiri igboro wi pe ijọba ti yi ohun pada lori irọloye awọn ọba naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI