Mo ṣetan lati du ipo gomina ipinlẹ Ondo - Ẹbiṣeni, akọwe agba fẹgbẹ Afẹnifẹre - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 5, 2024

Mo ṣetan lati du ipo gomina ipinlẹ Ondo - Ẹbiṣeni, akọwe agba fẹgbẹ Afẹnifẹre


Akọwe agba pata fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ṣọla Ẹbiṣeni ti sọ pe oun ṣetan lati du ipo gomina ipinlẹ Ondo lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2024, nitori pe oun nikan lun kaju oṣuwọn.
 
Ẹbiṣeni, lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, agbẹjọro naa to otun jẹ kọmiṣanna tẹlẹ nipinlẹ Ondo sọ pe oun mọ iṣoro to n doju kọ ipinlẹ ọhun, ati pe oun mọ ohun ti awọn araalu n fẹ.
 
O ni awọn gomina to ti jẹ sẹyin, ilana Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ ni wọn n tẹle, to si loun ṣetan lati mu ayipada rere ati idagbasoke ba ipinlẹ ọhun.
 
Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe asiko to lati wa ọna miran ti eto ọrọ ajẹ ipinlẹ ọhun yoo fi ni ilọsiwaju, dipo ki wọn maa duro de owo lati ọdọ ijọba apapọ, to si ni ọna abayọ kan ṣoṣo ti awọn le fi kuro ninu igbekun eto ọrọ aje niyẹn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI