Ọwọ ọlọpaa tẹ Bello, ogbologbo ajinigbe to pa ọlọmọge l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 28, 2024

Ọwọ ọlọpaa tẹ Bello, ogbologbo ajinigbe to pa ọlọmọge l'Abuja


Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ogbologbo ajinigbe ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Bello Mohammed niluu Abuja, to si ti n ka boroboro.
 
Mohammed ni wọn lo ji ọdọmọbinrin kan ti wọn pe orukẹ rẹ ni Nabeeha pẹlu awọn ẹgbọn rẹ gbe lagbegbe Bwari niluu Abuja lọjọ keji, oṣu yii.
 
Ai le san owo ti wọn n beere lo mu ki awọn ajinigbe ọhun pa Naheeba danu.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejọbi gbe ajde, o ni awọn ọlọpaa ẹkun Tafa to wa niluu Kaduna lo rọwọ Bello pẹlu miliọnu meji naira le diẹ, N2.25m.

Owo ọhun lo jẹ lara owo ti wọn gba ninu iṣẹ ijinigbe to yan laayo.
 
Adejọbi sọ pe Bello jẹwọ pe oun pẹlu awọn to ji awọn ẹbi Amofin Ariyo gbe ni Bwari, FCT, ti awọn si pa lara awọn ti awọn  jigbe.
 
Siwaju lo sọ pe awọn ajinigbe naa fi miliọnu kan naira bẹ awọn ọlọpaa lati fi wọn silẹ, ṣugbọn to lawọn ọlọpaa ọhun ko gba a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI