Oyun ni ayederu dọkita fẹẹ ṣẹ, lo ba gun alaboyun pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 4, 2024

Oyun ni ayederu dọkita fẹẹ ṣẹ, lo ba gun alaboyun pa


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti tẹ gendekunrin, ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Chidera Ugwu lori ẹsun wi pe o gun alaboyun kan pa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe iṣẹ awọn to maa n yọ oyun ti wọn ko fẹ ni Chidera yan laayo, to si ti ṣẹ ọpọ oyun danu.

Nigba to n fidi rẹ mulẹ, agbẹnusọ ọlọpaa Kano, SP Abdullahi Haruna Kiyawa jẹ ko di mimọ pe ogunjọ, oṣu kejila, ọdun to kọja ni wọn wa fi to wọn leti pe dọkita kan ti gun alaboyun pa.

Gẹgẹ bo ṣe salaye, o ni "logunjọ oṣu kejila, ọdun 2023 ni awa ọlọpaa gba ẹsun lati ọdọ ẹnikan to pe ara rẹ ni Nura Balarabe to n gbe ni ijọba ibilẹ Tofa ni Kano wi pe Ukasha Muhammed toun n gbe ni abule Langel, ijọba ibilẹ Tofa ni Kano fun aburo oun, ọmọ ọdun mọkandinlogun loyun.

"Awọn mejeeji yiii ni wọn wa pawọpọ lati gun aburo oun pa ki aṣiri ma ba a tu."

O ni niṣe ni wọn fun aburo oun ni oogun ati abẹrẹ pẹlu erongba lati jẹ ki oyun ọhun wa silẹ, ṣugbọn to jẹ pe niṣe lo pada gba ẹmi rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI