Gbajugbaja Wolii agbaye nni, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele to jẹ oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church lorileede Naijiria ti sọ pe oun ti ṣetan lati kọ mọṣalaṣi olowo iyebiye siluu Ekoo f'awọn musulumi.
Wolii Ayọdele lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Ọṣhọ Oluwatosin fi sita laipẹ yii.
Ninu atẹjade ọhun ni Wolii Ayọdele ti sọ ọ di mimọ pe lati mu iṣọkan ba ẹsin ati gbigba alaafia laaye lo mu koun ni erongba naa.
O sọ pe kii ṣe lati fi gba ogo tabi ki oun le maa fi gberaga loun ṣe pinnu lati kọ mọṣalaṣi naa, bi ko ṣe lati maa gbe orukọ Ọlọrun ga, nitori pe Ọlọrun ko mu ẹsin kan, ko yaẹsin miran sọtọ.
Wolii Ayọdele sọ pe nigba ti Jesu Kristi wa laye, ko waasu nipa ẹsin, bi ko ṣe pe nipa iwa ọmọniyan ati irẹlẹ, to si ni ko nii ṣe pe ẹnikan jẹ Kristẹni tabi Musulumi, bi ko ṣe pe ifẹ lo ṣe pataki, ṣaaju ohunkohun.
Siwaju sii lo sọ pe wi pe eeyan jẹ ẹlẹsin kan ko tunmọ si pe yoo wọ ijọba ọrun, bi ko ṣe pe ipa rere to ko lawujọ, ifẹ to fi han s'awọn eeyan gan-an ni ẹsin to ga julọ.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe oun ko nii jẹ gaba lori mọṣalaṣi naa, bi ko ṣe pe oun yoo fa a le awọn olori ẹlẹsin musulumi lọwọ lati maa ṣakoso rẹ nigba ti iṣẹ ba pari.
‘‘Mo nigbagbọ pe ko si ẹsin ni ọrun, ko si ohun to n jẹ Kristẹni tabi Musulumi lọrun. Awa ẹniyan la da ẹsin, o si ti jẹ ohun kan pataki to mu iyapa ba wa.
‘‘Mi o mọ idi pataki ti wọn fi da ẹsin silẹ, ṣugbọn o ti mu ipalara ba ẹda eeyan ju daadaa lọ.’
No comments:
Post a Comment