Ile-iṣẹ Adron Homes da oṣiṣẹ mẹwaa lọla pẹlu irin ajo afẹ lọ si Tanzania - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 2, 2024

Ile-iṣẹ Adron Homes da oṣiṣẹ mẹwaa lọla pẹlu irin ajo afẹ lọ si Tanzania


Yinni-yinni ki ẹni le ṣe omiran ni alaṣẹ ati oludasilẹ gbajugbaja ileeṣẹ to n ṣowo ilẹ ati dukia lorileede Naijiria, Adron Homes and Proterties Limited, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing fi ṣe fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ rẹ.

Laipẹ yii ni Aarẹ EmmanuelKing fi ontẹ lu irin ajo afẹ fun awọn oṣiṣẹ rẹ to peregede julọ nibi apero okoowo ti ọdun 2023, iyẹn ‘2023 Continental Business Challenge’.

Awọn mẹwaa naa la gbọ pe awọn igbimọ kan mu gẹgẹ bi ipa ti wọn ko ninu idagbasoke ati ilọsiwaju ileeṣẹ naa lọdun to kọja, paapaa julọ nipa awọn agbekalẹ to n mu itẹsiwaju ba ileeṣẹ naa.


Gbogbo ohun ti awọn oṣiṣẹ mẹwaa naa yoo nilo fun irin ajo afẹ lati lọ ni irọrun la gbọ pe ileeṣẹ Adron ko kalẹ fun wọn.

Ilu Zanzibar ni Tanzania l’awọn oṣiṣẹ mẹwaa naa yoo ti gbafẹ wọn, gẹgẹ bi ohun iwuri ti wọn n ṣe.

Ṣaaju ko to di pe awọn mẹwaa naa lọ wọ ọkọ baluu ni papakọ ofurufu Muritala Muhammad International to wa ni Ikẹja, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing gba wọn lamọran lati tubọ maa fi iwa ọmọniyan ṣe.


O ni ki wọn rii daju pe wọn ṣe amulo irin ajo naa gẹgẹ bi eyi ti yoo tun mu itẹsiwaju ba ileeṣẹ Adron Homes siwaju sii, ki wọn si jẹ aṣoju gidi ni gbogbo ibi ti wọn de.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI