Inu mi dun fun aami ẹyẹ nla yii - Olufọlakẹ AbdulRazaq dupẹ lọwọ ileeṣẹ iwe iroyin SUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 22, 2024

Inu mi dun fun aami ẹyẹ nla yii - Olufọlakẹ AbdulRazaq dupẹ lọwọ ileeṣẹ iwe iroyin SUN


Iyawo gomina ipinlẹ Kwara, Arabinrin Olufọlakẹ Abdulrazaq ti fi idunnu rẹ han lori bi ileeṣẹ iwe iroyin The SUN ṣe fi ẹbun aami ẹyẹ daa lọla gẹgẹ bi ipa to n ko lawujọ awọn obinrin nipinlẹ naa, ati lorileede Naijiria.
 
Olufọlakẹ AbdulRazaq ni iyawo gomina to peregede julọ lọdun 202, gẹgẹ bi awọọdu idalọla naa ṣe sọ.
 
Nigba to n fi idunnu rẹ han, Aṣiwaju awọn obinrin nipinlẹ Kwara naa sọ pe iwuri ati idunnu nla lo jẹ foun wi pe awọn kan mọ riri ipa toun n ko lawujọ.
 
O ni bo tilẹ jẹ pe oun yoo fi awọọdu ọhun jin fun Ọlọrun ọba, sibẹ o tun loun yoo fi jin awọn araalu ti wọn gbe iṣẹ oun yọ, nitori pe awọon gan an ni alatilẹyin oun.
 
Bakan naa lo ṣeleri pe awọọdu yii tun ti è oun nija lati ṣe ju boun ṣe n ṣe tẹlẹ lawujọ lọ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn iyawo gomina lorileede Naijiria


Bẹẹ lo tun ki gbogbo awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ gba aami ẹyẹ idalọla naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI