AbdulRazaq san gbogbo gbese ti Gomina Ahmẹd jẹ patapata awọn oṣiṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 4, 2024

AbdulRazaq san gbogbo gbese ti Gomina Ahmẹd jẹ patapata awọn oṣiṣẹ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti san gbogbo gbese ati ajẹẹlẹ ijọba ana labẹ iṣakoso Gomina Abdufatah Ahmẹd jẹ ko too gbe ijọba silẹ.

Gbogbo owo ti Ahmẹd jẹ awọn olukọ SUBEB ati awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ nipinlẹ naa ni Gomina AbduRazaq san tan patapata.

A gbọ pe biliọnu kan naira le diẹ, N1,297,389,165.83 ni awọn olukọ SUBEB san lati fi pa gbogbo gbese naa rẹ.
 
Bakan naa, biliọnu kan aabọ le diẹ, N1,622,673,992.12 naira ni owo ti AbdulFatah jẹ awọn oṣiṣẹ, ti wọn si ti gba gbogbo rẹ.
 
Ninu atẹjade ti Babatunde Toyin Abdulrasheed, akọwe iroyin nileeṣẹ to n ri sọrọ eto iṣuna gbe sita, o ni laarin oṣu kinni, ọdun 2020 si oṣu kinni, ọdun 2024, ijọba Kwara ti san gbese ti ko din ni biliọnu marun-un aabọ naira.
 
O ni gbogbo gbese yii lo jẹ owo ti ijọba ana jẹ awọn oṣiṣẹ SUBEB ati awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ.
 
Bakan naa lo tun fi kun un pe ijọba ti san owo oṣu fun awọn to ti gba igbega lẹnu iṣẹ wọn patapata.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI