Ile igbimọ aṣoju-ṣofin paṣẹ ki wọn lọ fi kele ofin gbe awọn alakoso Binace - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 4, 2024

Ile igbimọ aṣoju-ṣofin paṣẹ ki wọn lọ fi kele ofin gbe awọn alakoso Binace


Ile igbimọ aṣoju-ṣofin Naijiria ti paṣẹ pe ki awọon agbofinro lọ gbe awọn alakoso ileeṣẹ paṣipaarọ owo ori ayelujara ti wọn pe ni Binance.
 
Igbimọ to n ri si ọrọ eto iṣuna onijibiti (Committee on Finance) nile igbimọ aṣoju-ṣofin lo gbe aṣẹ naa kalẹ lonii, ọjọ Aje, Mọnde, lẹyin ipade ti wọn ṣe lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan ileeṣẹ naa.
 
Eyi ni igbesẹ tuntun ti yoo waye latigba ti ijọba apapọ ti fi ofin de ileeṣẹ Binance
 
Bi ẹ ko ba gbagbe, a gbọ pe ijọba Naijiria ti fi kele ofin gbe awọn alakoso Binance meji kan lori ẹsun gbigbe owo rin lọna aitọ ati jibiti ti wọn lu awọn eeyan.
 
Alaga igbimọ ọhun, Obinna Ginger ṣalaye pe awọn ti fi ẹnu ko lati sọ fun gbogbo ile lati fi ofin gbe awọn alakoso ileeṣẹ Binance yii.
 
O tẹsiwaju pe iwe ipe lati fi kele ofin gbe awọn alakoso yii lawọn yoo fi han awọn aṣoju-ṣofin.
 
Agbẹjọro ileeṣẹ Binance, Sẹnetọ Ihenyen, lo farahan niwaju igbimọ ọhun, nibi to ti fi iwe kan ti awọn alakoso kọ han wọn, ṣugbọn ti igbimọ naa sọ pe awọn ko ni gba bi oun ṣe farahan.
 
Ihenyen sọ pe awọn alakoso Binance n bẹru lati yọju si Naijiria, nitori ibẹru pe ijọba Naijiria yoo fi kele ofin gbe awọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI