Ilu Abẹokuta fẹẹ gba awọn alejo nla nitori ayẹyẹ ọjọ ibi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 1, 2024

Ilu Abẹokuta fẹẹ gba awọn alejo nla nitori ayẹyẹ ọjọ ibi


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ayẹyẹ ọjọ ibi gbajugbaja puromota nni to filuu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ṣebugbe, Oloye Arẹmu Bamgboye ti ọpọ awọn ololufẹ mọ si Ajiki-Olu.
 
Ọjọ karun-un, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii ni ayẹyẹ ọjọ ibi naa yoo waye luu Abẹokuta.
 
Iroyin to wa lọwọ sọ pe ẹsẹ ko nii gbero niluu Abẹokuta lọjọ naa, pẹlu awọn eeyan jankan-jankan, ọtọkulu lagbo oṣelu, ere tiata, to fi mọ oriṣiriṣi ẹka igbesi aye ni wọn ti n gbaradi lati wọ ilu naa wa.
 
AWIKONKO gbọ pe gbajugbaja onkọrin-binrin nni, Ọmọtoyọsi Kayọde Iyun Ajilọrẹ ti ọpọ mọ si St Janet ni olori ti yoo da awọn eeyan laraya lọjọ naa.
 
Gbọngan ayẹyẹ Providence to wa ni Lẹmẹ, opopona Abiọla-Way ni eto ayẹyẹ naa yoo ti waye.

Aṣọ alawọ goolu ati funfun (White and Gold) ni awọn eeyan yoo fi wọle lọjọ naa sinu gbọngan yii lati ba Ajiki-Olu yọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI