Ẹ da owo simẹnti pada si iye to wa tẹlẹ - Tinubu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, March 1, 2024

Ẹ da owo simẹnti pada si iye to wa tẹlẹ - Tinubu


Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti paṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ to n ṣe simẹnti lorileede Naijiria lati da iye owo ti wọn n ta bayii pada si eyi ti wọn n ta tẹlẹ.

Minisita fọrọ iṣẹ ode, David Umahi lo sọrọ naa jade lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Ṣokoto, lẹyin to ṣabẹwo si ileeṣẹ simẹnti BUA to wa nibẹ.
 
Ninu ọrọ rẹ, o ni 
 
“Aarẹ ṣi duro lori ipinnu wi pe ki owow simẹnti pada si iye to wa tẹlẹ, ko si le jẹ rira fun awọn mẹkunnu.
 
“Mo fẹẹ gba wọn niyanju lati duro lori ipinnu Aarẹ, ki a le mu erongba wa ṣẹ nipa ọrọ ile kikọ, ati ireti ọtun nipa awọon opopona to dara.”.
 
Bi ẹ ko ba gbagbe, ẹgbẹrun mẹta naira ni owo simẹnti tẹlẹ, ko to lọ soke si ẹgbẹrun marun-un naira. Ko tun pẹ rara ti owo simẹnti yii tun fi lọ soke si ẹgbẹrun mẹwaa ati ẹgbẹrun mẹẹdogun naira.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI