Wọn ju Bobrisky sẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 12, 2024

Wọn ju Bobrisky sẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara


Ile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa nipinlẹ Ekoo ti ju gbajugbaja Idris Okunẹyẹ ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Bobrisky sẹwọn oṣu mẹfa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Onidajọ Abimbọla Awogbọrọ to gbe idajọ ọhun kalẹ laarọ oni, ọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun 2024 sọ pe awọn ẹri toun ri gba fidi otitọ mulẹ.
 
Bakan naa lo sọ pe oun ko le fi aaye silẹ lati san owo itanran, bi ko ṣe pe ko lọ fi ẹwọn oṣu mẹfa ọhun gbara.
 
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ni wọn wọ Borbrisky lọ siwaju ile ẹjọ.
 
Ọjọ karun-un, oṣu kẹriin yii ni Bobrisky loun gba pe oun jẹbi ẹsun mẹrin ọtọọtọ ti wọn fi kan oun.
 
Lara awọn ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an ni ṣiṣe owo naira niṣekuṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI