Ilu Abẹokuta fẹẹ gbalejo awọn ọtọkulu lagbaye nitori ayẹyẹ ọjọ Aṣa lagbaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 11, 2024

Ilu Abẹokuta fẹẹ gbalejo awọn ọtọkulu lagbaye nitori ayẹyẹ ọjọ Aṣa lagbaye


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ti ayẹyẹ ayajọ ọjọ Aṣa lagbaye, ẹka ti ilẹ Yoruba to fẹẹ waye niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ kọkanlelogun, oṣu karun-un, ọdun 2024 ti a wa yii.

Lọdun 2001 la gbọ pe ajọ UNESCO buwọ ayẹyẹ ọjọ Aṣa lagbaye, ati pe ọjọ kan naa ni gbogbo orileede lagbaye yoo maa ṣe e, eyi ti wọn pe ni Universal Declaration on Cultural Diversity.

Gbọngan aṣa ipinlẹ Ogun, June 12 to wa lagbegbe Kuto niluu Abẹokuta ni eto ayẹyẹ naa, akọkọ iru ẹ yoo waye.

Ninu atẹjade ti ajọ ‘The Foundation for the Preservation of Yoruba Culture and Heritage’ gbe jade, eyi ti Ọgbẹni Kẹhinde Adebayọ Ṣomoye to jẹ alakoso ati Ọmọwe Tọla Adenẹkan, toun jẹ alaga igbimọ eto ayẹyẹ naa gbe sita, wọn ni ọpọ awọn agbaagba ilẹ Yoruba ni yoo wa niluu Abẹokuta.

Lara awọn agbaagba ti yoo wa nibẹ ni Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ; Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ni yoo wa nibẹ.

Awọn gomina ilẹ Yoruba bii Ọmọọba Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun, Ademọla Adeleke tipinlẹ Ọṣun, Lucky Aiyedatiwa tipinlẹ Ondo, Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ, Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ati Abiọdun Oyebanji tipinlẹ Ekiti.

Awọn ọba alaye bii Alake ilẹ Ẹgba, Akarigbo tilẹ Rẹmọ, Olu Ilaro, Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, Olowu tilu Owu, Ọṣilẹ Oke-Ọna ati awọn miran ni yoo wa nibẹ.

Oloye Lekan Alabi, Oloye Arabinrin Yẹmi Ọlanrewaju, Arabinrn Sherifat Olumuyiwa ati Ọnarebu Ṣẹgun Kaka ni yoo jokoo lati fọrọ jomitoro ọrọ.

Nibẹ ni wọn yoo ti yannanaa awọn iṣoro, ipenija to n koju aṣa ati eto aabo ilẹ Yoruba ati awọn ọba abayọ.

Olowu tiluu Owu, Ọba Ọjọgbọn Saka Matẹmilọla ni oludanilẹkọọ ọjọ naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI