Pẹlu erongba lati jẹ ki awọn araalu maa ni anfaani si eto.ilera to pe ye, ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe ohun yoo tubọ maa tẹsiwaju lati mu ayipada rere ba gbogbo awọn ile iwosan alabọde to wa nipinlẹ naa.
Igbesẹ ohun ni ijọba n ṣe labẹ eto ti wọn pe ni Basic Health Care Provision Fund (BHCPF), lati rii pe gbogbo awọn ile iwosan ijọba ni wọn ba ti igbalode mu.
Siwaju sii, ijọba jẹ ko di mimọ pe gbogbo ile iwosan alabọde ni Kwara ni awọn araalu yoo ti maa jẹ anfaani eto ilera to pe ye pẹlu owo ti ko nii ga wọn lara.
Nibi ifilọle eto ọhun ni ijọba ti fa iwe aṣẹ le awọn agbaṣẹṣe lọwọ lati bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ lai dawọ duro.
Ile iwosan alabọde mẹta ọtọọtọ ti iṣẹ atunṣe yoo ti bẹrẹ naa ni Adana PHC to wa nijọba ibilẹ Kaiama; Budo Egba PHC to wa nijọba ibilẹ Asa; ati Oke-Onigbin PHC, toun wa nijọba ibilẹ Isin.
Akọwe agba nileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ idagbasoke awọn ibudo eto ilera alabọde, Kwara State Primary Health Care Development Agency, Dokita Nusirat Elelu, jẹ ko di mimọ pe awọn agbaṣẹṣe to dantọ ni wọn gbe iṣẹ atunṣe awọn ile iwosan alabọde mẹtẹẹta naa le lọwọ.
Dokita Elelu ti alakoso ileeṣẹ eto iṣuna, iyẹn Personnel, Finance and Supply, Ọgbẹni Ajide Olayioye ṣapejuwe eto ọhun gẹgẹ bi apẹẹrẹ nla tuntun ti ijọba fẹẹ fi jẹ ki gbogbo araalu ni anfaani si eto ilera to pe ye nibikibi ti wọn ba wa.
No comments:
Post a Comment