Ẹgbẹ Ọdọ nilẹ Yewa, ipinlẹ Ogun ti pariwo sita wi pe awọn agbegbe ẹnubode ipinlẹ naa kii ṣe ibudo ti awọn oniṣẹ fayawọ fi n sapamọ si.
Awọn adari ẹgbẹ ọhun ti wọn pe ni Yewa Youths Progressive Movement (YYPM) ninu atẹjade ti wọn gbe jade laipẹ yii, ni wọn ti sọ pe ki awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri lọ jokoo jẹ.
Atẹjade naa ti alaga ati akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Adeoye Akinọla ati Sunday Adeyẹmi fi sita ni wọn ti ṣe ikilọ fun akọroyin oniṣẹ iwadii kan, Fisayọ Ṣoyọmbọ lati dẹkun kikọ iroyin ti ko ṣagbeleke agbegbe Yewa.
Wọn ni ki Ṣoyọmbọ dẹkun sisọ awọn agbegbe to wa ni Ogun West lorukọ gẹgẹ bii ibudo awọn onifayawọ tabi wi pe ko maa pe awọn ara agbegbe naa ni onifayawọ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn l'awọn ko lodi si bi ọkunrin akọroyin oniṣẹ iwadii naa ṣe n ṣiṣẹ rẹ, ṣugbọn ko ma ṣe gba ojusaaju laaye ninu iṣẹ iwadii rẹ nipa biba agbegbe kan lorukọ jẹ.
YYPM jẹ ko di mimọ pe iwa ti Ṣoyọmbọ hu nipa iṣẹ iwadii rẹ ti sọ awọn agbegbe ẹnubode ipinlẹ lorukọ gẹgẹ bii ibudo awọn onifayawọ, ati paapaa awọn olugbe ibẹ.
Wọn ni ọrọ ti ọkunrin naa kọ soju opo ayelujara rẹ laipẹ nipa wi pe wọn ti gbe awọn ọkọ to kun fun irẹsi ilẹ okeere silẹ lẹnubode, wọn si ti ṣetan lati ko wọn Naijiria, kii ṣe otitọ, bi ko ṣe erongba lati ba ilẹ Yewa ati Ogun West lorukọ jẹ.
Siwaju sii ni wọn sọ pe awọn agbegbe ẹnubode yii ni wọn ti ni idagbasoke nipa jijẹ ibi isadi fawọn onifayawọ ti wọn n wa lati oriṣiriṣi orileede si agbegbe ti wọn ti n ṣiṣẹ to ba ofin mu laarin orileede si orileede
YYPM fi kun ọrọ wọn pe latigba ti iṣakoso ana labẹ Aarẹ Muhammadu Buhari ti fofin de gbigbe irẹsi wọ Naijiria gba ẹnubode ilẹ ni awọn ọlọja ati oniṣowo lagbegbe naa ti ya sidi okoowo miran ti wọn fi n pawo sapo ara wọn.
Bakan naa ni wọn pe ọpọ awọn oniṣẹ ọwọ ni wọn ti bẹrẹ sii gbin irẹsi funra wọn lọpọ yanturu ni ibamu pẹlu ilana ijọba apapọ nipa jijẹ ohun ti a n gbin.
Bẹẹ ni wọn tọka sii wi pe awọn olugbe agbegbe naa, paapaa awọn ọdọ ni wọn ni ajọṣepọ pẹlu awọn ẹṣọ aṣọbode nipa gbigbogun ti iṣẹ fayawọ ati oniruuru okoowo to n ba eto ọrọ aje jẹ.
No comments:
Post a Comment