Aye ooo! Hamzat, gbajumọ ọlọkada l’Abẹokuta pokunso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 30, 2024

Aye ooo! Hamzat, gbajumọ ọlọkada l’Abẹokuta pokunso


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara adugbo Ọrẹmeji to wa lagbegbe Ijẹun-Titun, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ Ẹti, ọsẹ yii nigba ti wọn sọ pe ọmọkunrin kan ti gbẹmi ara rẹ lojiji.

Fatai Hamzat lorukọ ọmọkunrin naa ti wọn ba oku rẹ nibi to so ara rẹ kọ si ninu yara.

Nnkan bi agogo meje aarọ la gbọ wọn kofiri oku Hamzat ninu yara rẹ.

Ọkan lara awọn ara adugbo ni wọn lo kofiri ọkada Hamzat ninu ọgba ile rẹ, to si gbiyanju lati wo o. Ẹni naa kan ilẹkun titi, ṣugbọn ko ri ẹni da a lohun.

Idi ree to fi yọju loju ferese, to si ri oku rẹ nibi to kọ si loke. Ẹni naa lo lọ pe awọn eeyan ladugbo lati wa wo nnkan to n ṣẹlẹ.

Lẹyin naa la gbọ pe wọn fi ipa ja ferese ọhun wọnu yara Hamzat, to si jẹ kayeefi nigba ti wọn ba oku rẹ nibi to so ara rẹ kọ si nibi faanu.

Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa nigba to n sọrọ, ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti gbe oku naa lọ si mọṣuari fun ayẹwo ara oku ti a mọ si ‘autopsy’.

Odutọla sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lati mo idi pataki ti Hamzat fi gbẹmi ara rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI