Ileeṣẹ Adron Homes kede isunsiwaju idije ere idaraya ọdun 2024 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 28, 2024

Ileeṣẹ Adron Homes kede isunsiwaju idije ere idaraya ọdun 2024


Gbajugbaja ileeṣẹ to n ta ilẹ ati dukia nni, Adron Homes and Properties Limited ti kede wi pe awọn ti sun idije ere idaraya ọlọdọọdun wọn, iyẹn Adron Games ti ọdun 2024 siwaju.

Awọn alakoso ileeṣẹ naa lo fi iroyin ọhun lede ninu atẹjade ti alakoso agba, Adenikẹ Ajọbọ buwọlu lonii, ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2024.

Ninu atẹjade ọhun ni ileeṣẹ Adron Homes ti jẹ ko di mimọ pe awọn gbe igbesẹ naa nitori ifẹ awọn akopa, awọn alẹnulọrọ, ati awọn agbegbe ti idije ọhun ti fẹẹ waye.

Wọn ni awọn nilo lati sun idije ere idaraya naa siwaju nitori eto aabo to n kọ wọn lominu, ati pe aabo awọn oṣiṣẹ ati akopa ninu idije naa jẹ wọn logun pupọ.

"Gẹgẹ bi ileeṣẹ to mu ọrọ igbayegbadun awọn oṣiṣẹ, onibara oludowopọ ati awọn ti ọrọ kan lọkunkundun, o ṣe pataki lati gbaruku ti ọrọ eto aabo wọn ju ohunkohun lọ.

*Bakan naa, ileeṣẹ yii ti n lo anfaani naa lati tun erongba wa ṣe, ka si ṣe atunto lori agbekalẹ ere idaraya wa, lati rii pe gbogbo eeyan lo ni ipa rere ti wọn yoo ko, ti eto ọhun yoo si tun gbooro sii."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI