Gbajugbaja wolii nni, Wolii Israel Ọladele Ogundipẹ ti ọpọ awọn eeyan mọ si Genesis Global ti sọ pe ko oun le fi ipa tabi agidi mu awọn ‘ọmọ ijọ oun lati san owo idamẹwaa.
Wolii Gensis to jẹ alakoso ijọ Celestia Church of Christ, Genesis Global Parish lo sọrọ naa ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin PUNCH laipẹ yii.
Ninu ifọrọwerọ ọhun ni Wolii Genesis ti ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe gbogbo igba loun n san owo idamẹwaa toun, iyẹn ko tumọ si pe koun fi ipa mu awọn ọmọ ijọ oun lati maa san an.
“A maa n san idamẹwaa ninu ijọ wa. Mo maa n san idamẹwaa, ṣugbọn mi o kii fipa mu awọn ọmọ ijọ lati san idamẹwaa.
“Mo ti sọ ọ nigba kan ri; nko lọwọ si owo ijọ. A maa n lo idamẹwaa lati fi ran awọn opo lọwọ ninu ijọ wa ni. Ṣugbọn ohunkohun to le wu ki awọn eeyan maa fi owo idamẹwaa ṣe ninu ijọ wọn ko kan mi, mi o kii ṣe adajọ.”
Bakan naa, siwaju sii ni Wolii Ayọdele tun jẹ ko di mimọ pe awọn ile ifowopamọ ti figba kan wa ba oun ri lati ya owo, ati pe ki oun da owo naa pada lẹyin isọji ita gbangba ti wọn ba gbe kalẹ, ṣugbọn to loun ko gba fun wọn.
“Banki kan lo wa ba mi wi pe ki n wa ya owo, ṣugbọn mo sọ fun wọn pe nko lọkan gbese, paapaa lati ya owo.
“Nko sọ pe awọn ile ijọsin ti wọn n ya owo ni banki ṣe ohun ti ko dara. Awọn ile ijọsin kan wa ti wọn n ya owo, eleyi kii ṣe ẹṣẹ. Idi ti emi ko fi gba owo ele ni pe mi o ni ọkan rẹ.
“Mo nigbagbọ wi pe iṣẹ Ọlọrun yoo tẹsiwaju. Niwọn igba ti owo yiya naa ba ti n ṣiṣẹ fun wọn, ko kan mi. Awọn ile ijọsin miran n ya owo yii nitori pe wọn ko fẹ maa lọ awọn ọmọ ijọ wọn lọwọ gba.”
No comments:
Post a Comment