Lojuna lati ṣe iranwọ to yẹ fawọn araalu, ati lati mu wọn kuro ninu iṣẹ ati oṣi, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣagbekalẹ ironilagbara alaragbayida fawọn araalu lara ọtọ.
Bi eto ironilagbara naa yoo ṣe mu araalu kuro ninu iṣẹ ati oṣi, naa ni yoo tun ṣe anfaani pupọ fun eto ọrọ aje ipinlẹ Kwara, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Awọn olokoowo, ontaja, oniṣẹ ọwọ ati oniṣowo, to fi mọ awọn to ni ipenija ara ni yoo jẹ ninu eto ironilagbara yii kaakiri ipinlẹ naa.
Igbimọ amuṣẹṣe ti ijọba gbe iṣẹ ọhun le lọwọ la gbọ pe wọn ti bẹrẹ sii lọ lati tọwọ bọwe adehun pẹlu awọn alẹnulọrọ, lati fi idaniloju wọn han nipa erongba ijọba lati ṣe iranlọwọ fawọn araalu.
Lara awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ ti wọn wa nibi ipade to waye lọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja yii ni Jama’atu Nasril Islam (JNI), Christian Association of Nigeria (CAN), Muslim Youths Societies, Youth Wing Christian Association of Nigeria (YOWICAN), Coalition of Kwara North Groups (CKNG), Kwara South groups, Kwara Central groups ati Coalition of Kwara Civil Society Organisations.
Awọn miran ni Kwara Marketers, Kwara State Artisans Congress, Tricycle Owners Association of Nigeria (TOAN), Association of Independent Transporters (AIT), Allied Truck Transport Association of Nigeria (ATTAN), Road Transport Employee Association of Nigeria (RTEAN), Nigeria Union of Road and Transport Workers (NURTW), Haashim Initiative for Community Advancement (HICA), Women Wing of Christian Association of Nigeria (WOWICAN) and Muslim Women Societies, Center for Community Empowerment and Poverty Eradication (CCEPE), National Council for Women Societies (NCWS).
Gẹgẹ bi alaga igbimọ naa, igbakeji olori awọn oṣiṣẹ gomina, Ọmọọbabinrin Bukọla Babalọla sọ pe lara awọn igbesẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ni lati ṣe iranwọ fawọn araalu.
O ni ijọba n wa ọna lati ro ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara larugẹ, lati rii pe wọn kuro ninu iṣẹ ati oṣi.
No comments:
Post a Comment