Gbajugbaja onkọrin agbaye nni, David Adeleke ti sọ pe oun ko ri igbo mimu gẹgẹ bi egboogi oloro.
David Adeleke ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Davido sọrọ lori erongba ajọ alaanu rẹ fawọn ọmọ alailobi ati gbigogun ti aṣilo egboogi oloro nibi ifọrọwerọ ori ayelujara ti The Morning Hustle.
Davido sọ pe ọpọ awọn eeyan ma n ri oun pẹ oun n fa igbo, ṣugbọn to lounh ko ka a si egboogi oloro.
“Lọdun yiim mo fẹẹ ko owo silẹ lati gbogun ti aṣilo oogun ati egboogi oloro laarin awọn ọdọ. Nko ka igbo si egboogi oloro. Awọn kan maa n sọ pe mo maa n fa igbo, ṣugbọn nko ka igbo gẹgẹ bii egboogi oloro.
“Ọpọ eeyan lo n la oriṣiriṣi ipenija kọja. Fifi ara jin fun lilo egboogi ti wọpọ laarin awọn ọdọ lasiko yii. Fun idi eyi, mo fẹẹ ṣe iranwọ fun wọn lati le jẹ ki wọn jawọ.”
No comments:
Post a Comment