A ni lati mọ ohun ṣokunfa omiyale to yawọ oko irẹsi niluu Shonga - AbdulRazaq sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 27, 2025

A ni lati mọ ohun ṣokunfa omiyale to yawọ oko irẹsi niluu Shonga - AbdulRazaq sọrọ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ipinlẹ Kwara ti sọrọ, o ni awọn nilo lati ṣe iwadii, lati mọ ohun to ṣokunfa omiyale to yawọ inu oko irẹsi niluu Shonga, ijọba ibilẹ Edu.

Lọsẹ to kọja yii ni agbara nla yawọ inu oko irẹsi naa, to si ba gbogbo rẹ jẹ, leyi to ko awọn agbẹ sinu gbese ati ibanujẹ ọkan.

Nigba to n sọrọ, gomina sọ pe oun ti gbe igbimọ oluwadi dide lati tọpinpin ohun to ṣẹlẹ.

"Igbakeji olori awọn oṣiṣẹ gomina, Ọmọọbabinrin Bukola Babalola ni yoo jẹ alaga igbimọ ọhun. Awọn bii kọmiṣanna feto agbẹ, omi ati ayika; oludamọran pataki lori akanṣe iṣẹ; oludamọran pataki lori eto aabo, ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, NEMA ati awọn miran ni yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu alaga", atẹjade kan to tẹ wa lọwọ ṣalaye.

Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe awọn igbimọ yii yoo lọ s'awọn agbegbe ti agbara naa ti ṣọṣẹ, lati mọ bi ijamba ọhun ṣe pọ to, ti wọn yoo si tun fi ọrọ ibanikẹdun ijọba ranṣẹ si Emir ilu Shonga, Ọmọwe Haliru Yahyah Ndanusa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI