TESCOM gbe esi idanwo awọn ti wọn fẹẹ gba siṣẹ olukọ ni Kwara jade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 24, 2025

TESCOM gbe esi idanwo awọn ti wọn fẹẹ gba siṣẹ olukọ ni Kwara jade


Ajọ to n ṣakoso eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, ti wọn pe ni Kwara State Teaching Service Commission (TESCOM) ti gbe esi idanwo awọn akopa sita.

TESCOM ni gbogbo awọn to kopa ninu idanwo igbanisiṣẹ olukọ lopin ọsẹ to kọja yii le lọ yẹ ẹ wo lati mọ maaki ti wọn gba.

Idanwo ọhun lawọn akopa to le ni ẹgbẹrun mẹjọ aabọ (8,529) ṣe lori ẹrọ kọmputa

Alaga ajọ TESCOM nipinlẹ Kwara, Mallam Bello Taoheed sọ pe gbogbo awọn to jokoo fun idanwo naa ni anfaani lati lọ yẹ ẹ wo, ki wọn le mọ maaki ti wọn gba.

"Ipele akọkọ ree lẹyin idanwo naa. Ajọ yii yoo too gbe odiwọn maaki jade, lati mọ awọn to yege si ipele ifọrọwanilẹnuwo, ati awọn ohun miran," alaga naa jẹ ko di mimọ.

"Lẹyin idanwo ori kọmputa ti a mọ si CBT, gbogbo awọn to kopa kaakiri agbegbe ti a ya sọtọ fun idanwo naa jẹ 8,529. Atupalẹ awọn akopa naa ni: COED Ilorin, 2,891; Ilorin West LGA, 1,991; UNILORIN, 1,677; Lafiagi, 812; Offa, 586; Oko, 297; Patigi, 275. Apapọ awọn to forukọsilẹ ti a ranṣẹ pe jẹ 9,459. Awọn yooku ni wọn ko yọju fun idanwo.

"A maa kede igbesẹ to kan fawọn oluforukọsilẹ, to fi mọ gbedeke maaki, ọjọ ifọrọwerọ, ati awọn ohun miran."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI