Aafin Olu tiluu Orile-Ilawọ, Ọba Oluṣẹgun Alẹxandar MacGregor ti sọ ọ di mimọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin ti ọkunrin kan to pe ara rẹ ni Oluwaṣeun David Ogunsanya n gbe kaakiri nipa idajọ ile-ẹjọ kan, to si n pe fun irọloye kabiyesi naa.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin aafin naa, Ọgbẹni Lanre Ọlalẹyẹ fi sita lonii, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2025, o ni awọn ọrọ ibanilorukọ jẹ ti Ogunsanya n gbe kaakiri ori ayelujara lo jẹ irọ to jinna si otitọ.
O ni ọrọ ti asọdun ti ko lẹsẹ nilẹ ni awọn ẹsun ti Ogunsanya fi n kan Ọba MacGregor lori ayelujara, ninu iwe iroyin ati lawọn ileeṣẹ redio lo jẹ lati ba ọba naa lorukọ jẹ, ati pe awọn araalu mọ otitọ.
‘‘Ninu awọn apilẹkọ to n kaakiri ori ayelujara lẹnu ọjọ meloo kan sẹyin, eyi ti Oluṣeun Ogunsanya to pe ara ni dokita n kọ, nibi to ti sọ oriṣiriṣi ọrọ ibanilorukọ jẹ, to si n sọ pe ki awọn araalu kọ Ọba MacGregor gẹgẹ bi Olu tiluu Orile Ilawọ,’’ Ọlalẹyẹ sọ ninu atẹjade to fi sita.
Agbẹnusọ naa jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe aṣẹ ile-ẹjọ giga tipinlẹ Ogun to waye lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2025 tako Olu Orile-Ilawọ, o ni iyalẹnu nla lo jẹ wi pe Ogunsanya ko sọrọ nipa aṣẹ ile-ẹjọ kotẹmilọrun to da aṣẹ ile-ẹjọ giga nu lọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2025 titi digba ti ẹjọ yoo fi pari.
O ni aṣẹ ile-ẹjọ Kotẹmilọrun lo fẹsẹ mulẹ lasiko yii, nitori pe ile-ẹjọ naa ti da aṣẹ ile-ẹjọ giga to kọkọ waye nu, leyi to si fun Ọba MacGregor ni agbara lati maa ṣakoso gẹgẹ bi Olu tiluu Orile-Ilawọ.
Agbẹnusọ ọhun sọ pe niṣe ni Ogunsanya n fi aṣẹ ile-ẹjọ Kotẹmilọrun ṣere nipa sisọ fawọn eeyan lati ma ṣe ri Ọba MacGregor gẹgẹ bi Olu tiluu Orile-Ilawọ, ati pe bi ẹni to n yin agbado sẹyin igba lọrọ rẹ ri.
‘‘Ki lo de ti Ogunsanya wa n wa iranlọwọ awọn oloye ilu Ẹgba lori ọrọ to ti wa niwaju ile-ẹjọ?,’’ Ọlalẹyẹ beere, to si fi kun ọrọ rẹ wi pe ile-ẹjọ nikan lo laṣẹ lati sọrọ lori ẹjọ to ba wa niwaju rẹ.
‘‘O ti n lọ kaakiri ori redio, ayelujara ati awọn iwe iroyin lati maa gbe ayederu iroyin, irọ ati ọrọ abuku nipa Ọba MacGregor kaakiri, eleyi lo si jẹ ofuutufẹẹtẹ nitori pe awọn ara Ilawọ mọ otitọ. Wọn mọ ọba wọn, wọn ko si tẹwọ gba awọn ajagungbalẹ ti erongba wọn jẹ lati ko gbogbo ọrọ araalu Ilawọ lọ.
‘‘To ba jẹ lati daabo bo ohun ni jẹ biba awọn alagbara to fẹẹ ji gbogbo ogun ini awọn eeyan Ilawọ, a jẹ pe kabiyesi ko ni ẹbẹ kankan to fẹẹ bẹ awọn tọrọ naa ba ta ba, nitori to nigbagbọ pe awọn eeyan gbọdọ laju, ki wọn si gba ara wọn silẹ lọwọ awọn onimọ tara wọn nikan,’’ o sọ bẹẹ.
Bakan naa lo tun sọ pe ọrọ wi pe wọn da ayẹyẹ ọdun Egungun duro ko lẹsẹ nilẹ nitori pe lati ba kabiyesi lorukọ jẹ lasan ni, nitori ọdun ti kabiyesi ṣagbatẹru rẹ ni.
O wa gba Oluwaṣeun David Ogunsanya lamọran lati gbajumọ ọrọ ẹsun jibiti biliọnu kan naira to wa lọrun ẹgbọn rẹ, Lawrence Ogunsanya, dipo ko maa wa ọna lati ba kabiyesi lorukọ jẹ.
Ṣugbọn nigba toun naa n ba AWIKONKO sọrọ, David Ogunsanya jẹ ko di mimọ pe kii ṣe ẹsun jibiti biliọnu kan naira lo wa nile ẹjọ, bi ko ṣe ẹsun ibanilorukọ jẹ, eyi to sọ pe ile ẹjọ ko tii gbe yẹwo rara.
O ni oun ṣi duro lori wi pe ile ẹjọ ti rọ Ọba MacGregor loye, to si gbọdọ tẹle aṣẹ ile ẹjọ, ati pe ko tii si ile ẹjọ kankan to tii gba ẹjọ kotẹmilọrun ti kabiyesi gba wọle.
David ni ẹjọ Kotẹmilọrun ti ọba MacGregor pe, ile ẹjọ ko tii jokoo lori rẹ lati paṣẹ, to si ni aṣẹ naa ṣi f'ẹsẹ mulẹ titi di asiko yii.
O ni kii ṣe ẹsẹkẹsẹ teeyan ba gbe ẹjọ lọ siwaju ile ẹjọ ni awọn onidajọ maa n sare jokoo lori rẹ, bi ko ṣe pe wọn yoo tẹle ilana ko ti di pe wọn gbe igbesẹ to yẹ.
Bẹẹ lo rọ kabiyesi lati tẹle aṣẹ ile ẹjọ giga to ṣi wa nilẹ.
Nipa ti ọdun Ehungun, David ni ko too to asiko naa ni Kabiyesi ti kede si gbogbo araalu Ilawọ wi pe Egungun tabi Agan kankan ko gbọdọ jade niluu naa, nitori ọrọ eto aabo.
O ni Kabiyesi sọ pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe wọn gbe Egungun jade yoo fimu danrin ofin ijọba, nitori pe alaafia ilu lo jẹ wọn logun.
O ni ileeṣẹ redio Splash FM to wa niluu Abẹokuta ni wọn ti ka iroyin ikede naa sita fun gbogbo aye.
No comments:
Post a Comment