Awọn oba gbọdọ faramọ isinku nilana iṣẹṣe - Adajọ ile ẹjọ giga l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 30, 2025

Awọn oba gbọdọ faramọ isinku nilana iṣẹṣe - Adajọ ile ẹjọ giga l'Ogun

Onidajọ Phillips Akinside ti ile-ẹjọ giga nipinlẹ Ogun ti sọ ọ di mimọ pe gbogbo awọn ọba alaye gbọdọ faramọ isinku wọn nilana iṣẹṣe, eyi ti wọn mọ-ọn-mọ tẹwọ gba, ti wọn si darapọ mọ.

Adajọ Akinṣide lo sọrọ naa lọsẹ to kọja yii nibi eto idanilẹkọọ ti iranti Oloye Kẹhinde Ṣofọla, eyi ti wọn pe ni 'Chief Kehinde Sofola Memorial Bar Lecture', ẹlẹẹkarun iru rẹ to waye niluu Ṣagamu.

Eto ọhun ti ẹgbẹ agbẹjọro lorileede Naijiria, ti ẹkun Ṣagamu ṣagbatẹru rẹ, Akinṣide ni ẹni ti ko ba fẹ ki wọn sin oun nilana iṣẹṣe ko yẹ lẹni to n jẹ ọba alade.

O sọ pe niwọn igba ti eeyan ba ti di ọba ni ilana ati iṣe awọn eeyan, wọn ti juwọ gbogbo ohun to nii ṣe pẹlu ti wọn silẹ, wọn si ti darapọ mọ ti ilu, ko si ṣee ṣe fun wọn lati kuro nibẹ, koda titi di ọjọ iku.

“Bi yiyan tabi ifakalẹ ati ibuwọlu si ipo oye ba waye ni ilana iṣe ati iṣẹṣe awọn eeyan rẹ, o ti fi han pe gbogbo iwuye ati isinku gbọdọ waye nilana iṣẹṣe naa,” o ṣalaye.

O fi kun ọrọ rẹ pe “Awọn ọba ko ni aṣẹ tabi ẹtọ lati yi ilana iṣẹṣe ti wọn finufẹdọ wọnu rẹ pada. Labẹ ofin ilẹ Naijiria ti ọdun 1999, eeyan ni ẹtọ lati ṣe ẹsin to ba wu u.

“Wọn le bi eeyan si idile Kristẹni, ko si di Musulumi, tabi ki wọn bii si idile Musulumi, ko si di Kristẹni. To ba si yan ẹsin ibilẹ laaye, o ni anfaani lati ṣe e. Lẹyin to ba ti ṣe eyi tan, ko wa le yi awọn rẹ pada laarin meji, ko si wa maa ṣaniyan pe oun lẹtọ lati yi nnkan pada kuro ni bo ṣe ba a. O ti fi gbogbo iyẹn sẹyin tẹlẹ.”

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe ọrọ ki wọn maa gbe awọn baalẹ soke si ipo ọba kereje ti da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ laarin ilu.

O wa jẹ ko di mimọ pe awọn ọba kereje naa jẹ oloye ti wọn ko lagbara lati yan oloye ni agbegbe wọn.

Adajọ agba nipinlẹ Ogun, Onidajọ Mosunmọla Dipẹolu, wa gba awọn amọfin naa lamọran lati maa daabo bo ilana ofin ati lati maa daabo bo ẹtọ awọn ọmọniyan lawujọ dipo ilana iṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI