Gomina tẹlẹri nipinlẹ Kwara, Cornelius Adebayo ti jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọrin.
Aisan ọjọ ogbo ni iroyin fi to wa leti pe o ṣeku pa Adebayo, ẹni to fi tọkantọkan sin awọn ọmọ ipinlẹ naa nigba aye rẹ.
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq nigba to n kẹdun iku oloogbe naa sọ pe adanu nla ni ipapoda Ọlọlajulọ Adebayo jẹ fun ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade to fi sita, o ni ojiji ni iroyin iku naa tẹ oun lọwọ, nitori pe kii ṣe ohun ti wọn palẹmọ fun tẹlẹ.
"Pẹlu ibanujẹ ni mo fi gbọ iroyin iku Ọlọlajulọ gomina tẹlẹri, Cornelius Adebayo. Ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin ni," Gomina AbdulRazaq sọ ninu atẹjade.
"C.O. Adebayo la maa n sabaa pe e, to si jẹ akikanju gbogbo igba, alẹnulọrọ to ja fun rere ni gbogbo ọjọ aye re."
Siwaju sii ni gomina ba awọn mọlẹbi ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Kwara kẹdun, to si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oku naa si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment