Lojuna lati din gbogbo kudiẹkudiẹ ati awọn lati di awọn agbegbe to ṣofo lẹka ipawowọle ati owo nina nileeṣẹ Harmony Holdings ku, ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe igbesẹ tuntun ti bẹrẹ.
Awọn kudiẹkudiẹ yii ni wọn lo ti n ṣẹlẹ lẹka eto ipawowọle ileeṣẹ naa lati ọdun 2012 titi di asiko yii.
Ijọba Kwara ti wa sọ pe awọn yoo gbe gbogbo akoso Harmony Holdings fun ileeṣẹ eto iṣuna lati le maa ṣabojuto rẹ lọna to yẹ.
Nibi ipade awọn alakoso ipinlẹ naa ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq dari rẹ niluu Ilorin, Kọmiṣanna feto iṣuna, Ọmọwe Hauwa Nuru jabọ fun gomina ati igbimọ.
Wọn ni pẹlu bi wọn ṣe n ya owo lati na si ileeṣẹ naa, ko si ere kankan nibẹ.
Kọmiṣanna sọ pe gbogbo owo ilu ti wọn n pa nipinlẹ naa, ni wọn n na danu si ileeṣẹ Harmony Holdings, ti wọn ko si ri abayọri kanakant
O ni lara awọn ileeṣẹ bii Harmony Transport Services, Harmony Insurance Brokers, and Harmony Investment and Property Development Company ati awọn miran to wa labẹ Harmony Holdings ni wọn jẹ kokoro jẹwojẹwo lati ọdun 2012.
Nuru jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ kan ṣoṣo to n ṣe daradara julọ ni Harmony Securities Limited, nigba ti awọn yooku ko so eso rere.
O wa gba igbimọ naa lamọran lati tu igbimọ akoso Harmony Holdings ka, ki wọn si gbe e sabẹ akoso ileeṣẹ to n ri sọrọ eto iṣuna.
No comments:
Post a Comment