Gomina AbdulRazaq buwọlu ogun biliọnu naira lati tun ọpọ ile-ẹkọ ṣe kaakiri Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 8, 2025

Gomina AbdulRazaq buwọlu ogun biliọnu naira lati tun ọpọ ile-ẹkọ ṣe kaakiri Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara tun ti buwọlu owo ti ko din ni ogun biliọnu (₦20b) naira lati fi ṣe atunṣe lori awọn ile-ẹkọ to ti dẹnukọlẹ kaakiri ipinlẹ naa.

Awọn atunṣe naa ni yoo mu idagbasoke ati itẹsiwaju ba eto ẹkọ kaakiri ipinlẹ naa, nipa pipese agbegbe to dara fun awọn akẹkọọ lati kẹkọọ yo ye kooro.

Ninu atẹjade ti Peter Amogbonjaye to jẹ akọwe iroyin ileeṣẹ eto ẹkọ nipinlẹ naa fi sita, o ni igbesẹ naa lo bẹrẹ lati ọdun 2020 ti ijọba Kwara ti ṣatunṣe to yẹ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu ajọ Universal Basic Education eCommission (UBEC).

Atẹjade ọhun ti Kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọmọwe Lawal Olohungbebe buwọlu jẹ ko di mimọ pe iṣẹ akanṣe naa ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

"Ọlọlajulọ ti paṣẹ pe ki a tun fi ogun biliọnu naira miran bẹrẹ iṣẹ idagbasoke awọn ile-ẹkọ. Igbesẹ naa ti bẹrẹ. Awọn aworan naa ti wa nilẹ, a si maa bẹrẹ loju ẹsẹ ti wọn ba ti buwọlu eto iṣuna naa," Kọmiṣanna sọ eyi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI