Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele, ti rọ Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu tilẹ Naijiria lati ṣọra gidigidi fun Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump.
Wolii Ayọdele sọ pe gbogbo erongba Donald Trump lasiko yii ni lati yọ Aarẹ Tinubu nipo, to si rọ Tinubu lati sun ṣokoto rẹ soke gidi.
Agba Wolii naa lo sọrọ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Oluwatosin Ọṣhọ fi sita laipe yii, to si ni aarẹ Amẹrika ti mu Tinubu sinu igbekun lati yọ ọ danu.
O ni gbogbo iranlọwọ ti ilẹ Amẹrika n ṣe fun Naijiria lori gbigbogun ti aisi eto aabo ni lati raaye wọnu ijọba, ki erongba wọn le wa si imuṣẹ.
“Trump ti fi aake kọri lati yọ Aarẹ Tinubu. Ilẹ Amẹrika yoo wa lara awọn ti yoo dide lodi si Tinubu. Ẹ le ma rii bayii gẹgẹ bi wọn ti ṣe fi han mi, idi ree ti mo fi n sọ pe Trump n wa ọna lati yọ Tinubu, lẹyin eyi, ko s’ohun miran mọ,” Wolii Ayọdele sọ bẹẹ.
Siwaju sii lo ni ipinnu aarẹ ilẹ Amẹrika kii ṣe lati gbogun ti ọrọ eto aabo nikan, bi ko ṣe lati doju ijọba bolẹ.
“Naijiria yoo ṣi tẹsiwaju lati maa gbogun ti iṣoro eto aabo, ṣugbọn boya wọn maa ja tabi rara, gbogbo afojusun Trump ni lati yọ Tinubu kuro nipo, ṣugbọn Tinubu ko tii mọ bayii.”
O wa rọ Aarẹ Tinubu lati gbe igbesẹ oṣelu ti yoo bori gbogbo erongba aarẹ ilẹ Amẹrika, pẹlu ikilọ pe bi ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ, erongba Trump yoo pada yọri si rere.
Bakan naa ni alaṣẹ INRI tun jẹ ko di miọ pe asọtẹlẹ kan ti wọn n gbe kaakiri nipa oun, kii ṣe lati ọdọ oun, iyẹn eyi ti wọn sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Mozambique yoo doju Naijiria bolẹ nibi idijẹ AFCON to n lọ lọwọ.
Wolii Ayọdele sọ pe ko si igba kankan toun fi asọtẹlẹ naa sita, ati pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ṣi asọtẹlẹ oun gbọ.
“Mo ri iroyin kan ti wọn sọ pe emi ni mo fi asọtẹlẹ naa sita. Mo fẹẹ fi to gbogbo eeyan leti wi pe asọtẹlẹ naa ko wa lati ọdọ mi rara. Nko mọ bi wọn ṣe sọ pe emi ni mo fi asọtẹlẹ ọhun sita. Irọ nla ni.
“Lati ọdun pipẹ sẹyin ni awọn eeyan ti n ṣi asọtẹlẹ mi gbọ, ti wọn si n kọ ohun ti mi o sọ jade, pẹlu erongba awọn oniroyin ori ayelujara lati fi pa owo. Mo wa fẹẹ fi to o yin leti pe ohun ti wọn kọ yii, agbelẹrọ, ayederu pọmbele ni.”
No comments:
Post a Comment