Bi eto idibo ọdun 2027 ṣe ti n sunmọ etile kaakiri Naijiria, ti iṣakoso awọn gomina kan si n d'opin, lai ni anfaani lati lọ fun saa kẹta, eyi ti ṣi anfaani tuntun silẹ f'awọn iṣakoso tuntun.
Lara awọn gomina to n lọ, ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara.
Ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress kaakiri Naijiria ṣeto ipade gbogboogbo wọn, nibi ti wọn ti yan awọn alakoso tuntun ti yoo tukọ awọn ẹgbẹ naa fun saa ọdun mẹta.
Nibi eto naa to waye nipinlẹ Kwara, ni Gomina AbdulRazaq ti sọ pe iṣakoso oun ti ko ipa ribiribi to jọju ninu idagbasoke ati ilọsiwaju ẹgbẹ naa.
AbdulRazaq loun nigbagbọ pe pẹlu gbogbo iṣẹ takuntakun toun ti ṣe silẹ, oun nigbagbọ pe iṣakoso to n bọ lẹyin oun yoo gbe iṣẹ naa nibi toun ba ba a de.
Nigba to n sọrọ nipa awọn ẹka to ti ṣiṣẹ akanṣe, gomina sọ pe idagbasoke to ti de ba eto ẹkọ, eto ilera, igbayegbadun araalu, eto ọrọ aje ko lafiwe.
“A ni lati ki ara wa ku oriire fun ibi ti irin ajo naa de, wi pe a tun le pade nibi layọ ati alaafia lonii. Maa sọ pe a ti ṣe daadaa,” Gomina sọ bẹẹ.
“A ti wa lasiko oṣelu bayii. Mo lero wi pe a ti ṣe daadaa, daradara gidigidi. Fun bi ọdun mẹfa le, a ti ṣe aṣeyọri to lọọrin nipa iṣẹ idagbasoke ju bi a ṣe ba a lọ. Gẹgẹ bi ẹyin naa ṣe le rii, ẹgbẹ oṣelu alatako ti fori ṣanpọn nipinlẹ Kwara, sibẹ a ko nii duro.
“A ni lati ṣiṣẹ takuntakun daadaa, ka si tun ṣiṣẹ le eyi ti a ti ṣe silẹ, ko ma ba a parun.”

No comments:
Post a Comment