“Ẹyin alejo pataki, ẹyin akọroyin, obinrin ati ọkunrin. Lakọkọ, mo dupẹ lọwọ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu to jẹ olori apaṣẹ gbogbo eleto aabo nilẹ Naijiria fun agbekalẹ ileeṣẹ eleto aabo tuntun ti 'Operation Savannah Shield', eyi to kaakiri ipinlẹ which will cover the entire Kwara State ati apa kan ni Niger," Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ eyi nibi eto ifilọlẹ to waye laipẹ yii.
"Eyi ni yoo jẹ ifọkanbalẹ nla fun gbogbo awa ti a n gbe ni agbege ti wọn yoo ti maa ṣiṣẹ.
"A ti ri bi awọn agbebọn aṣekupani ṣe n ṣọṣẹ lawọn agbegbe bii Ariwa Kwara, Guusu Kwara ati awọn aap kan ni ipinlẹ Niger lati bi ọdun kan le diẹ.
"Ṣugbọn a tun ti rii pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti dide, ati pe eto aabo ti lọ soke lawọn agbegbe yii, ti ohun gbogbo si ti pads bọ sipo.
"Ṣugbọn ṣa, agbegbe Ariwa Kwara ṣi n jẹ ipenija, idi ree ti a fi ṣagbekalẹ 'Operation Savannah Shield' ti a n ṣe ifilọlẹ loni.
"Mo dupẹ lọwọ olori awọn oṣiṣẹ aabo to jẹ ki eyi ṣee ṣe ni kiakia. O tu wa lọkan pupọ, nitori pe gbogbo awọn eeyan wa ni wọn n sun oorun asundọkan bayii," Gomina sọ bẹẹ
No comments:
Post a Comment