Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti ba alaga ijọba ibilẹ Ifelodun, Alaaji Abdulrasheed Femi Yusuf kẹdun iku mama rẹ to jade laye lojiji.
Aisan to nii ṣe pẹlu ọjọ ogbo ni wọn lo ran mama naa, Alaaja Shiffahu Aduke Yusuf lọ sọrun aremabọ lọjọ Aiku to kọja yii, ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2026.
AbdulRazaq ninu atẹjade ibanikẹdun to fi ranṣẹ si gbogbo mọlẹbi, lo ti gbadura pe ki Adẹdaa tu wọn lara.
Bẹẹ ni gomina tun gbadura pe ki Ọlọrun fi ori jin mama naa, ko si tẹ si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment