Aṣiri tu! Wọn ni Saraki ti n bẹbẹ kaakiri, ko ma baa foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 23, 2026

Aṣiri tu! Wọn ni Saraki ti n bẹbẹ kaakiri, ko ma baa foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan


Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii, ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe agba oloṣelu nni nipinlẹ Kwara, Sẹnetọ Bukola Saraki ti n bẹru lati fi aṣọ pemep roko ọba lori ẹsun ipaniyan tijọba ipinlẹ naa fi kan an.

Sẹnetọ Saraki to ti figba kan ri jẹ aarẹ ile igbimọ aṣofin nilẹ Naijiria, gomina tẹlẹ nipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed, ati awọn miran la gbọ pe ijọba Kwara fi ẹsun ipaniyan kan wọn.

Ẹsun naa lo nii ṣe pẹlu ikọlu awọn adigunjale si awọn ile ifowopamọ to wa niluu Offa lọdun 2018.

Bo tilẹ jẹ pe latigba ti ijọba Kwara ti kede ẹjọ naa sita, ni Sẹnetọ Saraki ati awọn ọmọlẹyin ti n sọ pe ko si nnkan to fẹẹ ṣẹlẹ, ati pe aṣilo agbara ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq n lo.

Ṣugbọn ni bayii, pẹlu ohun tp ṣẹlẹ laipẹ yii, o ti fi han gbangba wi pe ẹri ọkan ti n jẹ agba oloṣelu ọhun, lori bi wọn ṣe lawọn ọmọ ẹyin rẹ n bẹbẹ lati da ẹjọ naa nu.

Nibi iwọde kan ti wọn lawọn ọmọlẹyin Saraki, ti wọn tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP ṣe laaarọ Ọjọbọ, oni, ni wọn ti n rawọ ẹbẹ si aarẹ ẹgbẹ IEDPU, Alaaji Abdulmumin lati paṣẹ fun ijọba ipinlẹ naa lati jawọ ninu ẹjọ ọhun.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 ni igbẹjọ ọhun yoo waye nile ẹjọ giga tipinlẹ Kwara.

Awọn ọmọ ẹyin naa ni wọn ti n paroko alaafia bayii, lati rawọ ẹbẹ sijọba ati awọn alẹnulọrọ ni Kwara, ko le jawọ ninu ẹjọ ipaniyan ọhun.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI