Bọsun Adeoye
Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ Ori Oke Ina ati Iṣẹ Iyanu (MFM) kaakiri agbaye, Ọmọwa Daniel Kolawole Olukoya ti tu aṣiri tuntun nipa idi ti awọn ọkunrin fi n kuna ninu ipo adari.
Ọmọwe Olukoya rọ awọn ọkunrin lati bẹrẹ sii fi iwa Ọlọrun ati iwa ọmọluabi ṣiṣẹ ti wọn ba gba, to si ni eyi ni ipilẹ rere lati ṣe aṣeyọri.
Olori ijọ MFM naa lo sọrọ yii nibi ipagọ awọn adari, iyẹn “2026 Leaders Retreat of MFM God’s Men of Valour (GMOV)”, eyi ti wọn pe akori rẹ ni Agbara fun Ogo Tuntun (Power for Fresh Glory), eyi to waye ninu gbọngan Oore Ọfẹ, iyẹn Grace Hall to wa ninu ọgba olu-iya ijọ naa laipẹ yii.
Nigba to n sọrọ lori akori to pe ni Iṣoro awọn Adari Ọkunrin to n kuna (Problems of Failed Male Leaders), Ọmọwe Olukoya tọka si awọn ohun to n fa ikuna laarin awọn ọkunrin.
O ni awọn nnkan bi wiwa ni ipejọ ti ko yẹ, ṣiṣe ipinnu to lodi ati aigba amọran to tọ, maa n fa ki ọkunrin kuna ninu ipo adari.
Agba ojiṣẹ Ọlọrun naa sọ pe iwa bi Ọlọrun, ikọra-ẹni-nijanu, ṣiṣe otitọ ati awọn ohun rere miran lo le jẹ ki ọkunrin ṣe aṣeyọri ninu ipo to ba di mu, yala ninu ile ni tabi ni awujọ.

No comments:
Post a Comment