L'Ọjọbọ, ọsẹ yii ni Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tẹwọ gba awọn kọkọrọ ati iwe ẹri awọn ile alabọde ti ijọba apapọ kọ, lati bẹrẹ iṣakoso lori rẹ, fun igbayegbadun awọn araalu.
Awọn ile naa to wa labẹ eto ti wọn pe ni National Housing Programme Estate lo wa niluu Ogbondoroko, ijọba ibilẹ Asa, ni ijọba apapọ fa gbogbo aṣẹ rẹ le ijọba ipinlẹ Kwara lọwọ.
"A wa nibi lọsan oni (Tọside), lati tẹwọ gba awọn ile ti ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri sọrọ ile gbigbe ati idagbasoke ilu kọ pari, eyi ti ijọba ipinlẹ Kwara ti ra," Gomina AbdulRazaq sọ bẹẹ nibi eto ayẹyẹ naa.
Nigba to n gba ẹnu gomina sọrọ, kọmiṣanna fọrọ eto ile gbigbe ati idagbasoke ilu, Ọmọwe Segun Ogunsola, jẹ ko di mimọ pe awọn ile tuntun naa yoo mu ẹdinku ba iṣoro ile gbigbe ti awọn araalu n koju.
"Igbeṣe miran tun ree lati di alafo to wa lẹka ile gbigbe, ati ipesẹ ile fun awọn olugbe ipinlẹ Kwara. Awọn ile wọnyi lo jẹ mejilelaadoje (132), to si wa ni oniruuru lati yara kan si meji, si mẹta, to si jẹ aladagbe," o sọ bẹẹ.
Minisita naa, Ahmed Musa Dangiwa ninu ọrọ tiẹ ṣalaye pe erongba ijọba apapọ ni lati di gbogbo alafo to wa laaarin awọn onile lori ati awọn alainile lori kaakiri Naijiria, paapaa ipinlẹ Kwara.

No comments:
Post a Comment