Ko yẹ ki awọn agbesunmọmi, ajinigbe de ile-ẹjọ ki wọn to pa wọn – Wolii Ayọdele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 26, 2026

Ko yẹ ki awọn agbesunmọmi, ajinigbe de ile-ẹjọ ki wọn to pa wọn – Wolii Ayọdele


Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ ijihinrere ti ẹmi ti INRI (INRI Evangelical Spiritual Church) Wolii Elijah Babatunde Ayọdele, ti sọ pe ẹnikẹni ti wọn ba ka iwa ọdaran igbesunmọmi ati ijinigbe mọ lọwọ yẹ ki wọn pa wọn loju ẹsẹ ni, kii ṣe pe ki wọn foju wọn ba ile-ẹjọ.

Wolii Ayọdele rọ ijọba apapọ lati fagile gbigbe awọn ajinigbe ati awọn agbesunmọmi lọ sile-ẹjọ lojuna lati jẹ ki wọn jiya ẹṣẹ wọn.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Wolii Ayọdele, Oluwatosin Osho fi sita lọjọ Aiku, oni, o sọ pe ọna kankan ti iwa igbesunmọmi ati ijinigbe le gba dinku lorileede Naijiria niyẹn.

Siwaju sii ni agba wolii naa sọ pe ki wọn fọwọ ofin gbe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe o n ba awọn agbesunmọmi ati ajinigbe dunadura, ati paapaa awọn gomina to n san owo lati gba awọn eeyan silẹ lọwọ awọn ọbayejẹ naa.

“Ko yẹ ki ile-ẹjọ wa fun awọn ajinigbe ati agbesunmọmi; kete tọwọ ba ti tẹ wọn, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe iṣẹ ti wọn n ṣe niyẹn, loju ẹsẹ ni ki wọn ti pa wọn. Ko si idi kankan lati gbe wọn lọ sile ẹjọ nitori pe wọn ko nii gba idajọ to tọ si wọn.

“Iru iwa ọdaran bẹẹ yẹ ko jẹ idajọ iku ẹsẹkẹsẹ, ati pe awọn to n ba wọn sọrọ lati san owo naa ni ki wọn gbe; ọna ti iwa igbesunmọmi ati ijinigbe le gba dopin niyẹn,” Wolii Ayọdele sọ bẹẹ.

Ojiṣẹ Ọlọrun naa wa gbe oṣuba kare fun ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria fun akitiyan wọn, paapaa fun ti aṣẹ ti minisita feto aabo gbe kalẹ wi pe ki wọn maa pa awọn ajinigbe ati agbebọn loju ẹsẹ.

O wa rọ Aarẹ Tinubu lati bu ọla fun awọn ọmọ ogun ti wọn n ja lati gbogun ti iwa igbesunmọmi ati ijinigbe, to fi mọ awọn olori ologun.

Wolii naa ni agba wolii yii tun rọ ijọba lati ma ṣe foju tẹmbẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo ibilẹ ati aladani, to si jẹ ko di mimọ pe wọn nilo iranlọwọ ijọba apapọ nipa ironilagbara lati gbogun ti oniruuru iwa ọdaran.

“Ileeṣẹ ologun tun ṣi le ṣe daadaa sii; awọn kan wa ti wọn n gbe igbesẹ lati doju ijọba bọle nipa aisi aabo. Mo gbe oṣuba kare fun fun minisita feto aabo lori aṣẹ "yinyin ibọn loju ẹsẹ bi wọn ba foju kan awọn agbesunmọmi ati ajinigbe; bi wọn ba ti ṣe bẹẹ ri, iwa igbesunmọmi yoo dopin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI