Oludije sipo Aarẹ ilẹ Naijiria lọdun 2027 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress, NDC, Peter Obi, ti sọ pe oun ko ṣetan lati san owo fun ẹnikẹni lati fi ra ibo lọdun to n bọ.
Peter Obi sọ pe ki oludibo kankan ma ṣe ro wi pe oun yoo fun wọn lowo lati di ibo foun, nitori pe ohun ti ko bae to oṣe awa-ara-wa mu ni.
Obi lo sọrọ yii llasiko abẹwo to ṣe lọ si aafin Emir tiluu Sokoto lọjọ Aje, ọsẹ yii.
Nibẹ ni Peter Obi ti gbe ipolongo idibo rẹ lọ fun awọn ara ipinlẹ naa, lati fi erongba rẹ han nipa eto idibo apapọ orileede Naijriria lọdun 2027.
O ni ki awọn aṣoju ẹgbẹ lawọn ibudo idibo ma ṣe lero wi pe oun yoo ko owo kalẹ lati fi ra ibo, lati dibo foun.
NIgba to n dahun oniruuru ibeere nibi ipade ita gbangba to ṣe ni Sokoto, Obi jẹ ko di mimọ pe adari rere loun, toun si gbọdọ maa fi apẹẹrẹ rere lelẹ.
Gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra naa sọ pe iwa ki awọn oloṣelu maa fi owo ra ibo lọjọ idibo wa lara awọn nnkan to n da kun iṣẹ ati oṣi to n ba ọmọ Naijiria finra.
“A ko ṣetan lati fun awọn aṣoju ẹgbẹ ni ibudo idibo lowo. Fifi owo ra ibo niyẹn jẹ, eyi si wa lara idi pataki to n jẹ ki iṣẹ ati oṣi maa pọ si lorileede yii,” Obi ṣalaye.
O fi ọkan awọn eeyan balẹ wi pe eto aabo to pe ye yoo wa lasiko eto idibo, ati pe gbogbo ibo ti awọn araalu ba di, ni wọn yoo ka finnifinni.
Peter Obi pẹlu igbakeji rẹ, Rabi’u Kwankwaso ni wọn jọ lọ.

No comments:
Post a Comment