Ọdun Ọlọjọ: Ọọni Ifẹ bẹrẹ igbele ọlọjọ meje - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 22, 2026

Ọdun Ọlọjọ: Ọọni Ifẹ bẹrẹ igbele ọlọjọ meje


Alaga igbimọ awọn ọba alaye lẹkun Iwọ-Oorun Naijiria, Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti bẹrẹ igbele ọlọjọ meje, lati fi bẹrẹ eto ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ to n bọ lọna.

Ọọni Ifẹ, Ọjaja keji lo wọnu igbele naa ninu aafin rẹ to wa nílùú Ile-Ifẹ nipinlẹ Ọṣun.

Irọlẹ ọjọ Aiku to kọja ni Ọba Ogunwusi, Arole Oodua bẹrẹ eto igbele naa, gẹgẹ bi ọkan lara awọn alakalẹ eto ayẹyẹ naa.

Atẹjade ti alakoso eto iroyin Ọọni, Sodiq Lawal fi sita, lorukọ Ọtunba Moses Olafare, o sọ pe Ọọni yoo lo asiko naa lati fi ṣe ọpọlọpọ adura fun orileede Naijiria, ati lati fi wa oju rere Ọlọrun fun alaafia, isokan ati idagbasoke orileede.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI