Adron Homes gbe igbimọ iṣakoso tuntun kalẹ fun "Treasure Park Gardens Phase 2 Extension" - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 21, 2026

Adron Homes gbe igbimọ iṣakoso tuntun kalẹ fun "Treasure Park Gardens Phase 2 Extension"


Ileeṣẹ Adron Homes ti gbe igbimọ iṣakoso tuntun kalẹ fun ẹka ile gbige wọn ti wọn pe ni "Treasure Park & Gardens Phase 2 Extension"".

Awọn igbimọ naa yoo maa ri sọrọ awọn to ni dukia ninu ọgba ileeṣẹ naa ti wọn pe ni "Adron Homes Property Owners and Residents Associations (AHPORA)".

Ninu atẹjade ti awọn alakoso fi sita lọjọ Iṣẹgun to kọja, Adron Homes jẹ ko di mimọ pe igbimọ ọhun ni yoo maa ri si ibaṣepọ laaarin ileeṣẹ ati awọn olugbe agbegbe naa tii ṣe ẹkun "Uptown and Downtown".

Ifilọlẹ igbimọ tuntun naa ni yoo fun awọn lanlọọdu lanfaani lati sọ erongba wọn, agbekalẹ wọn ati amọran pẹlu awọn alakoso Adron Homes fun idagbasoke ati ayipada rere.

Bakan naa ni igbimọ ọhun yoo tun maa ri si ohun gbogbo to n lọ ninu ọgba naa, lati le rii pe awọn olugbe ri iranlọwọ gba lasiko.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI