Agbalagba radarada; awon omoomo e ladugbo lo n fipa ja ibale won - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 28, 2017

Agbalagba radarada; awon omoomo e ladugbo lo n fipa ja ibale won

Boroboro ni won ni baba agbalagba radarada ti won pe ni Alosuposo Louis, eni odun marundinlaadorin nka lago olopaa lojobo Tosde to koja yii, eni ti won fesun kan pe o fipa ja ibale awon omo keekeeke meji kan tojo ori won ko ju mejo si mewaa lo nilu Ilaro.

Louis
Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni iya okan lara awon omo ti baba agbaya naa fipa ja ibale e lo lo so fawon olopaa lojobo Tosde ose to koja lati wa fi owo ofin muu.

Won so pe obinrin naa leyin to sakiyesi isesi omo e, to je odun mejo pe ayipada kan ti de si lara, lo beere pe ki lo sele sii.

Ariwo "aye dami loro" ni won lobinrin naa pe, to si bere sii pariwo kaakiri adugbo naa, kawon eeyan too pe lee lori lati mo nnkan to n sele.

AWIKONKO gbo pe, loju ese lawon araadugbo naa ti ya lo sile baba agbaya, eni odun marundinlaadorin naa lati lo pariwo lee lori.

Kayeefi loro naa je nigba ti won dele baba ti won dele baba ti won poruko e ni Alosuposo bi iya miran naa tun se mu omo e, to je odun mewaa de pe baba naa ti fipa ja ibale oun naa.

Okan lara awon to gbo nipa isele naa ni won loo so pe ki won lo foro naa to awon olopaa leti. Lesekese ni won ni oga olopaa ti won loro so fun, Ogbeni Makinde Kayode ti lewaju awon olopaa to lo gbe baba naa nile.

Nigba to n jeri sisele naa, Ogbeni Abimbola Oyeyemi to je agbenuso olopaa nipinle Ogun so pe looto ni, atipe awon ti fesunkan an lesekese, eyi ti ko ni pe ti yoo fi foju bale ejo.

O so pe won ti gbe awon omo naa lo si jenera osibitu lati fo inu fun won, ki won si toju eon lona to ye.

Oyeyemi tun so pe, bakanna lawon tun ti rowo to awon akekoo ojewewe meta kan, ti won je akekoo ileeko girama Ajagbe High School ti won fipa ba okan lara awon akekoo won sun. o ni baba omo naa lo wa fejo sun awon olopaa.

Bee lo wa fi kun oro e pe awon ko ni dawo duro lati maa gbogun ti iwa odaran nipinle Ogun, nitori pe, alaafia awon araalu lo je awon logun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI