Ileepo Rabeng to jona l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 27, 2017

Ileepo Rabeng to jona l'Abeokuta


Titi di bi a ti n ko iroyin yi lawon ebi awon to jona mo ileepo kan ti won pe ni Rabeng, to wa ladugbo Adigbe nilu Abeokuta lojobo Tosde ose to koja si fi wa ninu ibanuje.

Gege ohun taa gbo nipa isele ijanba ina naa, ni nnkan bi aago mokanla aabo laaro ojo nisele aburu naa waye nigba ti eon so pe afefe gaasi lo sokunfa sababi ina naa.

AWIKONKO gbo pe, eni to nileepo naa taa foruko bo lasiri lo ranse pe weda (welder) lati wa ba oun jo irin afefe gaasi ileejo naa nitori pe o n jo gaasi danu.

Inu ogba ileepo naa ni won so pe weda naa ti wa sise, laimo pe ewu to wa nibe le mu emi lo, ko si fi dukia sofo.

Ko tii to iseju marun ti won so pe weda naa bere ise irin afefe gaasi to wa jo, ko too dipe o sesi da irin naa lu, "Gbau" ni won so pe ina la lesekese lati ibi to ti n jo irin naa wonu tanka ti won n ro afefe gaasi si, eyi ti won ri mole sinu ileepo naa.

Lara awon toro naa soju e, to ba akoroyin wa soro so pe, awon araadugbo ni won won ranse sawon panapana atawon eso alaabo ilu, iyen sifu-difensi to fi mo Fijilante atawon olopaa ni won ranse pe.

AWIKONKO gbo pe, kawon osise panapana too de lati wa dawo ina naa duro, eeyan meji ti dagbere Faye, tawon meje si farapa yannan-yannan, eyi ti won lomo kekere kan, eni odun meje naa wa nibe.


Ohun ti a tun gbo ni pe, yato si ileepo Rabeng to jona yi, oko akeru dangariya kan ti won pe ni Toyota, okada, soobu itaja merin, bakanna lawon eru to le ni milionu naira naa jona peluu.
Won so pe, lesekese tawon panapana atawon Fijilante ti de ni won ti bere sii fi omi pa ina naa, sugbon ki won too dawo e duro, nnkan ti baje koja aala. Won lori ko olakada ti okada e jona yo, nigba to fo danu lati ori okada to wa nibi to ti n ra epo bentiro.

Bakanna la gbo pe awon alaanu to wa lagbegbe naa ranse sileese pajawiri nileewosan ijoba to wa ni Ijaye lati wa gbe oku awon tori tako nibi ijamba ina naa.

Ogbeni Akinwande Aboluwoye to je oga agba ajo sifu-difensi nipinle Ogun, nigba to n soro so pe, awon kan ni won ranse pea won pe ileepo kan n jona l’Adigbe, ko too di pe oun so fawon eeyan oun lati lo tete sabewo sibe, o nigba tawon maa fi de be, ile ti we, gbegede ti gbina.

Okunrin naa so pe, o seni laanu pe awon meji lo ba isele naa, nigba tawon meje naa si farapa basu-basu. O ni lesekese lawon ti ranse pe awon eka to n ri si isele pajawiri ni osibitu ijoba to wa ni Ijaye, ti won si wa gbe awon oku, atawon to farapa lati gba itoju.

Aboluwoye so pe, ero generato tokunrin naa n lo nitori ibi ti won ri afefe gaasi si, lo sokunfa ijamba ina naa.

Adari eka to n ri si isele pajawiri, iyen State Emergency Management Agency, SEMA, Ogbeni Shakiru Adebakin, so pe afowofa lo fa ijamba ina naa. O ni kani eni to ni ileepo naa mo nipa ilana to so po mo oro ina ni, boya iru nnkan bayii ko nii sele.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI