Nitori YAYI: Amosun da Damochee duro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 18, 2017

Nitori YAYI: Amosun da Damochee duroOgunpola Damilola

Orisirisi awuyewuye lo ti jeyo lori ipinya ojiji to de saarin gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ati okan lara awon osise lori oro iroyin, Ogbeni Ogunpola Damilola Damochee.

Bawon kan se n so pe se lokunrin naa, iyen Damilola Damochee deede fipo naa sile ni nitori itiju iro ti gomina Amosun n fi gbogbo igba pa fawon araalu, ko si tesiwaju ninu igbesi aye tuntun lati doju ko ise e, bee lawon kan n so pe, se lokunrin naa tele amoran tawon kan n fun pe ko tete pada leyin oga e, Amosun.
         
Awon kan na tun so pe gomina Amosun gan an fun ra e lo jawe lo gbele e fokunrin naa nitori pe o ti dale, o n gbeyin bebo je. Won lo ti je eewo Amosun.

AWIKINKO gbo pe okunrin naa ti n ledi apo po pelu Senato Adeola Solomon topo mo si YAYI to n soju ekun kan l'Ekoo nile igbimo asofin agba nilu Abuja, eyi tawon kan ti n fun lonte pe oun ni yoo di gomina ipinle Ogun lodun 2019.

Fawon to ba mo bo se n lo nipinle Ogun, won yoo mo pe bi ata ati oju loro gomina Amosun pelu Senato YAYI naa ri. Awon mejeeji ko gbati ara won fun iseju aaya, bi tile je pe Senato naa ko ni ikunsinu pelu Amosun.

Gege bi AWIKONKO tun se gbo nipa omo bibi Owu naa, iyen Damilola, won lawon kan ni keefin e nile itura kan nilu Abeokuta, to si je pe Senato YAYI naa wa nibe lakoko naa, eyi lo fa ti won se foro naa to eni kan to sunmo Gomina Amosun bi isan orun leti.

Eni naa la gbo pe o so fun Gomina Amosun, toun naa si ran awon eeyan lati lo wo boya looto ni. Won ni nigba tawon yen debe, won rii pe ipade kan lokunrin naa lo ba YAYI se.

Bee la tun gbo pe, bi Damilola se de ofiisi lodo Gomina Amosun, ni gomina beere lowo e pe nibo lo ti n bo, sugbon okunrin naa so pe oun lo gbafe nile itura kan to wa layika ni. Loju ese ni won so pe gomina ti pase pe ko kowe fise sile lai beere ohunkohun.


Sugbon Damochee nigba to n dahun ibeere lori Facebook so pe, oun deede fipo naa sile lati koju mo ise oun ni, tawon kan ti won ko gba ti Gomina Amosun si n fokunrin naa se yeye pe o ti ronupiwada lati pada leyin Amosun nitori ko fe ko boun loruko je.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI